Pastor Omotoso Oluwatobi, CAC Iwo: Lẹ́yìn ìsọjí '21 days' tí a ṣe ni wọ́n jí wa gbé

Àkọlé fídíò, Pastor Omotoso Oluwatobi, CAC Iwo: Lẹ́yìn ìsọjí 21 days tí a ṣe ni wọ́n jí wa gbé

Ajinigbe fun wa ni ẹgbkrun kan náírá àti 'touch light'ki a fi maa rin lọ lẹ́yìn ti wọngba owo itusilẹ lọwọ ẹbi wa- Oluwatobi Omotoso

Wọ́n yìnbọn pa Ọlọ́dé àti Bàbá kan kí wọn to pada tu wa sile

BBC wa pasitọ ijọ CAC , Oke Isegun ni ilu Iwo Isin ni ipinle ?Kwara ti awọn ajinigbe ji ti won si pada tu silẹ kan.

Pasito Oluwatobi omotoso salaye bi o se pari isọji tan ti o si n lọ sile ki wọn to kọluu loju ọna ti wọn si jii gbe.

Pasitọ naa sọ ohun ti oju oun ati Maneja ile epo LAOP-Dam Global ati ọlọde ti wọn jọ jigbe ri ki wọn to pa ọlọde ati baba agba kan to tan ina ninu ile rẹ.

O ni pe ọgbọn milionu ni wọn kọkọ sọ pe ki ẹbi awọn lọ wa ki Olodumare to ko si wọn ninu ti wọn fi pada gba milionu marunn.

Oga ọlọpaa Okasanmi Ajayi to jẹ alukoro ileeṣẹ ọl\'opa ni Kwara naa só si ọrọ pe ọlọpaa sọ pe ko si epo ati ohun ija nigba ti wọn pe wọn lori iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni Oba Tunde Olutade to jẹ Oniwo ti ilu Iwo Isin naa ṣalaye ohun tuntun ti ilu n ṣe fun awọn eleto aabo lati fopin si iru iṣẹlẹ bẹẹ ti ko waye ri.