Adedibu ti mọ̀ pé ọ̀lọ́jọ́ ti dé lọ́jọ́ tó kú, ó ní àpò ẹ̀wà kàn ni ká fi dín àkàrà láì mọ̀ pé àkàrà òkú rẹ̀ ni - Bose Adedibu
Awọn idile Agbaoye oloselu nilẹ Ibadan ati ilẹ Yoruba ni apapọ, Oloye Lamidi Ariyibi Adedibu salaye irufẹ eeyan ti Baba naa jẹ lẹyin ọdun mẹdogun to jade laye.
Ọdun 2008 ni Adedibu jade laye lasiko to n lọ iwe irina rẹ ni ọfisi iwe irinna to wa niluu Ibadan.
Ileeṣẹ BBC News Yoruba kan si Aya oloogbe, Iyafin Abosede Adedibu ati Akọbi oloogbe, Dokita Abass Adedibu lati mọ nipa bi nnkan se ri lẹyin ti Baba Adedibu jade.
Lasiko aye Adedibu,, Iyafin Abosede ni ojojumọ ni awọn maa n gbe apẹrin lena nitori bi ero se ma pọ ninu ile ọhun, ti wọn wa ki Baba Adedibu.
Iyafin tẹsiwaju pe ijọ ti ọkọ ohun jade laye, o pe oun pe ki oun sọ fun alase pe apo ẹwa kan ni ki wọn fi se akara lọjọ naa.
O salayei bi ipapoda naa se waye
"Wọn lọ se ayewo ara wọn lọdọ Dokita wọn niluu Eko, koda mo ba Dokita naa sọrọ lati Ibadan, ti a si se awada,
"To si ni awọn jọ se awada bayii pe ko si nkan to se Baba, pe agba ni o.
"Baba ma rin irinajo lẹẹkan lọdun lati lọ wo awọn ọmọ wọn, ti wọn si ti n mura ati lọ, mo wa ri pe iwe irina wọn ko lọjọ lori mọ.
"Mo ransẹ si awọn ọmọ ti wọn jọ lọ pe ki wọn ba lọ si ibudo iwe irinaa, lati lọ se iwe irinna naa.

"Mi ko mọ pe ọjọ naa ni wọn ma lọ si ibẹ, bi wọn se n ti Eko bọ ni wọn gba ibẹ lọ, lati ibẹ ni Ọlọrun ti wọn tan si.
Iyawo Adedibu ni o dabi pe Baba naa ti mọ pe oun yoo jade laye lọjọ nitori ohun to bẹrẹ fun ni jijẹ lọjọ naa.
"Awọn agbalagba maa n sọ pe ti eeyan ba fẹ ku, o sese ko ti mọ.
"Lọdun naa wọn pe mi ki wọn to lọ si irinajo naa pe ki sọfun awọn alase mi pe apo ẹwa kan ni ki wọn din, pe gbogbo wa, akara ni ma jẹ ọlọjọ yẹn.
"Mo ni akara lọsan, wọn ni nnkan ti awọn fẹ niyẹn, ta o mọ pe akara yẹn naa ni a ma wa din fun wọn lọjọ naa."

Ki se gbogbo oloselu lo le kuku iru iku ti baba to bi ku- Ọjọgbọn Abass Adedibu
Akọbi Baba Adedibu, Dokita Abass Adedibu ni inu ohun ma n dun pe Baba to bi ohun ku iku re nitori ki n se gbogbo oloselu ni yoo ku iru iku ti Lamidi Adedibu ku.
O tẹsiwaju pe gbogbo awọn oloselu ti awọn mọ ni Naijira, pupọ ninu wọn ni awọn agbenipa ma sekupa tabi ti wọn ku iku ijamba ọkọ.
"Baba mi ku iku re, Iwa Baba lo jẹ ki Baba mi ku iku ire nitori pe ẹni ti ko ba ni iwa to daa, ko ni ku iku ire.
Abass Adedibu sọrọ lori nkan to fa ti awọn eeyan fi dikun ni ile Adedibu lẹyin to jade lọdun 2008 ati bi ayipada se ba ile ọhun.
"Ọrọ ile aye, ohun ti wọn ba fẹ jẹ ni wọn o jẹ lọdọ rẹ, ti wọn ko ba ri ẹ mọ, wọn a dẹyin lẹyin rẹ ni.
"Gbogbo awọn mii to jẹ pe baba ti ran lọwọ, meloo melo ninu wọn ni a n ri ninu ile Baba.?
"Awọn to ba jẹ pe wọn ni ibẹru Ọlọruin ni wọn si n wa si ile Baba."
Ki lo sẹlẹ laarin Adedibu ati Ladoja?

Ọmọ Baba sọrọ nipa aawọ to waye laarin Oloye Rasidi Ladoja, to jẹ gomina tẹlẹri nipinlẹ Oyo ati Baba Lamidi Adedibu.
O ni "Ija laarin Sẹnẹtọ Ladoja to jẹ ẹgbọn si mi ati Baba to bi mi, ọmọ ni Sẹnẹtọ Ladọja si baba.
"Awọn oloṣelu, wọn mọ iwa ara wọn, ohun to o de sẹlẹ laarin awọn mejeeji, ko ba ti yanju ti Baba ba si wa laye,
"Awọn eeyan lo tun da sii, nitori pe wọn a gbọ ti ọdọ ẹgbọn mi Ladoja, wọm a lọ sọ fun baba to bi mi, wọn a gbọ ti baba to bi mi, wọn a lọ sọ fun ẹgbọn mi Ladoja."
Ọrọ pọ lẹnu Dokita Abass Adedibu, ẹ wo fọnran yii.