Kí ló fa gbas-gbos láàrín Gbenga Daniel àti Dapo Abiodun ní ìpínlẹ̀ Ogun?

Gbenga Daniel

Oríṣun àwòrán, others

Ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun ti sọ pe gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Otunba Gbenga Daniel ko ṣatilẹyin kankan fun Bola Ahmed Tinubu lati de ipo Aarẹ.

Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti ẹgbẹ naa n fesi si ọrọ Daniel pe, gomina Dapo Abiodun n gbogun ti oun latari pe oun ṣatilẹyin fun Tinubu lasiko eto idibo abẹnu ipo Aarẹ APC lọdun 2022.

Ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ APC ipinlẹ Ogun, Olusola Ogunsanya fi lede, o ni irọ patapata ni gbogbo ohun ti Daniel sọ ninu ifọrọwerọ to ti tahun si gomina Abiodun.

"Irọ ni Daniel pa, ko ṣatilẹyin kankan fun Tinubu"

O ni ko si ibi kankan ti Daniel ti ṣatilẹyin fun Tinubu.

Atẹjade naa tun sọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni gomina tẹlẹ ọhun ṣatilẹyin fun lasiko ibo Aarẹ.

O sọ siwaju si pe asiko Daniel ti n di ohun igbagbe ninu eto oṣelu Naijiria amọ gomina Abiodun lo tun jẹ ki awọn eeyan gbọ orukẹ rẹ, ati pe Aarẹ Tinubu ti kilọ fun gomina tẹlẹ naa pe ko jawọ ninu iwa ọdalẹ amọ ko gbọ.

O ni “ti a ba ni ka wo ti oju ti awọn eeyan fi wo gomina nigba kan ri naa, ko yẹ ka fun un lesi ọrọ yii.”

“Awada kẹrikẹri ni bi bo ṣe sọ pe Dapo Abiodun kii ṣe ara ọmọ ẹgbẹ lọdun 1998 si 1999, gbogbo eeyan lo si mọ pe oun funra rẹ lo da ẹgbẹ ru lọdun 2003 ko to di gomina labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu PDP.”

“Ko si akọsilẹ kankan pe pe Daniel lọwọ si bi Tinubu ṣe di gomina lọdun 1999.”

“Lọdun 2003, o dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, kii ṣe AD...”

“Odidi ọdun mẹjọ lo fi ṣejọba labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ki Ibikunle Amosun to gba ijọba lọwọ rẹ, eyii ti ko mu ko jẹ nnkan mọ.”

Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ

Gbas-gbos yii bẹrẹ lẹyin ifọrọwerọ Gbenga Daniel pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle ThisDay, nibi to ti ṣalaye nipa ohun to fa ipinya laarin oun ati Dapo Abiodun.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ija waye laarin oun ati Abiodun latari bi oun ṣe ṣatilẹyin fun Bola Tinubu lasiko idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu naa.

Ti ẹ ko gbagbe, ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ogun ko ṣe ipolongo ibo fun Gbenga Daniel lati du ipo sẹnetọ, amọ o pada wọle.