Àwọn ọba ṣe ètò àdúrà lórí ìlera Gómìnà Akeredolu

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Ẹgbẹ awọn lọbalọba nipinlẹ Ondo ti ṣeto adura fun gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu, lati tete sàn ninu ailera rẹ.

Eto adura naa waye ni gbọngan Cocoa Confrerence Hall ni ọfiisi gomina niluu Akure.

Lati oṣu diẹ sẹyin ni iroyin ti n jade pe ipo ilera Gomina Akeredolu ko dara.

Aipẹ yii si ni gomina funra rẹ fa iṣakoso le igbakeji rẹ, Lucky aiyedatiwa lọwọ, ko le ni anfaani lati mojuto ilera rẹ.

Nibi eto adura naa ni awọn ọba naa ti sapejuwe gomina gẹgẹ bi ogo ipinlẹ Ondo, to si ti ṣe awọn nnkan pataki fun ipinlẹ naa paapaa nipa eto aabo ati awọn nnkan amayedẹrun.

APC sọ òkò ọ̀rọ̀ sáwọn alátakò lórí ipò ìlera Akeredolu! Àlàyé nípa ipò tó wà nìyí

“O ba ni lọkan jẹ pe awọn kan le maa ro iku ro eniyan ẹlẹ́ran ara bii tiwọn. Iru iwa yii ko tọ o si yẹ ki gbogbo eniyan to ba fẹ ni bu ẹnu atẹ lu u.”

Eyi ni ọrọ to jade wa latọdọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress(APC) ìpínlẹ̀ Ondo gẹgẹ bi wọn ṣe bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ́ alátakò lori ikọlu ọrọ ti wọn ṣe si ẹbi Gomina Rotimi Akeredolu ati ipenija ailera to n koju lọwọlọwọ.

Adari iroyin ati ọrọ to kan araalu ni APC, Steve Otaloro fi ẹsun kan awọn alatako ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si Ileeṣẹ iroyin Channels pe ẹgbẹ́ alatako ni awọn mọ̀lẹ́bí gomina o ṣe to lati mojuto ilera rẹ amọ wọn ko tii fi ẹkúnrẹ́rẹ́ alaye nípa eyi han.

"Iru ọrọ bẹẹ jẹ irọ ko si bọ̀wọ̀ fun ni, ọrọ aburu si ni pẹlu," Otaloro sọ bẹẹ.

O fi ẹsun kan awọn kan pe awọn ni wọn ń gbe iroyin ofege kiri ati gbọ́yii sọyii nipa pe olodii gomina ti dagbere faye.

Agbenuso ẹgbẹ́ òṣèlú naa ṣe apejuwe pe ipo ilera Akeredolu kii ṣe eyi to buru to bẹẹ ti ko ni jẹ ko le pada si ẹnu iṣẹ rẹ gẹgẹ bii gomina Ìpínlẹ̀ Ondo.

Bakan naa, Iroyin ni alaga ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni Ondo, Ade Adetimehin naa da si ọrọ ọhun to si pe fun adura fun gomina ati idile rẹ.

Ṣáájú ni ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yii ni gomina gunle irinajo lati lọ bojuto ilera rẹ to si gbe ìṣàkóso ìjọba le igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa lọwọ.

“Gomina Ìpínlẹ̀ Ondo Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu tí n ba awọn ọrọ ilera kan finra laipẹ yìí.”

“O wa ṣe pataki lati mọ wipe ipo ilera rẹ kii ṣe eyi to buru to bẹẹ ti ko ni le pada si ẹnu iṣẹ rẹ gẹgẹ bii gomina Ìpínlẹ̀ Ondo.”

O ni pẹlu gbogbo eleyi, awọn alaburu ẹda kan tun yoo tun maa ro ero iku si eniyan bii tiwọn.

Amojúẹ̀rọ Ade Adetimehin to fi aidunu rẹ han si iroyin to n tan kaakiri yii wa pe fun atilẹyin ati adura fun gomina ati idile rẹ wípé òun ti Arakunrin Akeredolu nilo lasiko yii ni.