Wo àwọn ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan nínú iṣẹ́ Hajj

Awon ero ninu Kaabah

Oríṣun àwòrán, Others

Ọ̀kan lára òpó márùn-ún tó gbé ẹ̀sìn Islam ró ni lílọ sí Hajj jẹ́.

Ohun ni opo karùn-ún èyí tó kẹ́yìn nínú òpó tí ẹni tó bá jẹ́ Mùsùlùmí gbọ́dọ̀ tẹ̀lé tó sì jẹ́ dandan fún gbogbo Mùsùlùmí.

Ní ìlú Mecca ní orílẹ̀ èdè Saudi Arabia ni Hajj ṣíṣe ti máa ń wáyé ní ọdọọdún tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Mùsùlùmí káàkiri orílẹ̀ èdè àgbáyé sì máa ń péjọ sí láti ṣe ìjọ́sìn wọn.

Hajj ṣíṣe pọn jẹ́ ọ̀ranyàn fún Mùsùlùmí lọ́kùnrin àti obìnrin tó bá ti bàlágà (dàgbà), tó ní owó lọ́wọ́, tó sì tún ní àlàáfíà pípé láti lọ ní ẹ̀ẹ̀kan.

Lílọ sí Hajj ju ìgbà ẹyọ̀kan lọ kìí ṣe ohun tó burú rárá níwọ̀nba ìgbà tí ènìyàn bá ní owó rẹ̀ lọ́wọ́ tí àláfíà rẹ̀ náà sì pé pérépéré.

Ìgbàgbọ́ àwọn Mùsùlùmí ni pé tí ènìyàn bá ṣe iṣẹ́ Hajj gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ nínú ìwé mímọ́ Àlìkùránì, gbogbo nǹkan tí àwọn bá béèrè fún ní Hajj ló máa wá sí ìmúṣẹ àti pé gbogbo ṣẹ̀ṣẹ̀ tó bá ní lọ́rùn ni Ọlọ́run máa parẹ́ fun.

Ṣíṣe Hajj jẹ́ ohun iduunu fún àwọn Mùsùlùmí tó sì tún máa ń jẹ́ àsìkò tí wọ́n ní láti fi sún mọ́ Ọlọ́run.

Ìgbà wo ni iṣẹ́ Hajj máa ń wáyé?

Ní ọdọọdún, láàárín ọjọ́ kẹjọ sí ọjọ́ Kejìlá oṣù Dhul Hijjah tó jẹ́ oṣù Kejìlá nínú kajọ́ kaṣù àwọn Mùsùlùmí ni iṣẹ́ Hajj máa ń wáyé ní pàtó.

Ní ọdún 2023 tí a wà yìí, ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kẹfà ni àwọn ọjọ́ yìí bọ́ sí.

Káàkiri gbogbo àgbáyé, àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjì àbọ̀ ló máa ń ṣe ìrìnàjò lọ sí Makkah nínú oṣù Dhul-Hijjah láti lọ ṣe Hajj.

Ta ló le lọ fún Hajj?

Ẹni tó bá jẹ́ Mùsùlùmí ni Àlìkùránì ní ó pọn dandan fún láti lọ sí Hajj.

Ẹni tó bá fẹ́ ṣe Hajj gbọ́dọ̀ jẹ́ àgbàlagbà tó ti tó ojú bọ́ fúnra rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí aburú nínú kí àwọn ọmọdé náà lọ fún Hajj, kìí ṣe dandan fún wọn.

Bákan náà ẹni tó bá fẹ́ lọ fún Hajj gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ìlera rẹ̀ dúró ire. Àwọn arúgbó àtàwọn tó ní ìpèníjà ìlera, tí wọ́n ń ṣe àárẹ̀ kò lẹ́tọ̀ọ́ láti lọ fún Hajj.

Ẹni tó bá ń lọ fún Hajj kò gbọ́dọ̀ jẹ ènìyàn lówó nílé kó tó lọ fún Hajj àyàfi kó san gbogbo gbèsè tó bá wà ní ọrùn rẹ̀.

Àmọ́ sá ènìyàn tó jẹ gbèsè tún le lọ sí Hajj tí ẹni tó jẹ lówó bá gbà á láyè láti lọ tàbí tí Hajj tó ń lọ náà kò ní di lọ́wọ́ láti san gbèsè tó bá jẹ.

Àwọn ìgbésẹ̀ wo ló wà nínú iṣẹ́ Hajj?

Nǹkan àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì fún ẹni tó bá fẹ́ ṣe Hajj ni láti kọ́kọ́ dàníyàn wí pé òun ń lọ fún Hajj láti lọ sin Ọlọ́run Ọba tó dá a.

Fún àwọn tó bá ti lọ sí Hajj ni ọjọ́ tó pẹ́ díẹ̀ kí iṣẹ́ Hajj tó bẹ̀rẹ̀, Umrah ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń ṣe.

Àsìkò Umrah yìí ni wọ́n máa ń Tawaf, tí wọ́n yóò sì tún sá Safa àti Marwa, tí wọ́n yóò sì tún ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà kí iṣẹ́ Hajj tó bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.

Wíwọ aṣọ Háràmí

Ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Dhul-Hijjah ni iṣẹ́ Hajj máa ń bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú pẹ̀lú wíwọ aṣọ Háràmí.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹfà ni ó bẹ̀rẹ̀ fún àwọn tó ń ṣe Hajj ọdún 2023.

Ní kété tí wọ́n bá ti wọ aṣọ Háràmí yìí, ẹni tó bá ń ṣe Hajj kò ní ẹ̀tọ́ láti sọ̀rọ̀ òdì, ṣépè, gé èékánná, gẹ irun tàbí fa sìgá.

Bákan náà ni onítọ̀hún kò ní àǹfàní láti pa ohunkóhun tàbí lo tùràrí tó bá ní òórùn.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí ní ka Talbiyah tí gbogbo wọn yóò sì kóra jọ pọ̀ sí Mínà lábẹ́ òrùlé kan tí wọ́n ti pèsè kalẹ̀ fún wọn.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Àlùkùránì, abẹ́ òrùlé yìí ni wọ́n máa wà tí wọn ti máa kí gbogbo irun ọjọ́ náà títí di ìdájí ọjọ́ kejì tí í ọjọ́ Arafah.

Ọjọ́ Arafah

Awon to wa lori oke Arafah

Oríṣun àwòrán, Others

Lẹ́yìn tí ilẹ̀ bá ti mọ́ bá wọn ní Mínà ni wọ́n máa gbéra lọ sí òkè Arafah ìyẹn ní ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Dhul-Hijjah.

Àwọn alálàá jì ma ma tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Ọlọ́run bí wọ́n bá ṣe ń gòkè Arafah bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n máa ma ṣe ìjọ́sìn fún Ọlọ́run.

Orí òkè Arafah yìí ni wọ́n máa ti kirun Dhur àti Asr, tí wọ́n sì máa gbọ́ wáàsì ní Mọ́sáláṣí al-Nimra.

Ọjọ́ Arafah jẹ́ ọjọ́ tó ṣe pàtàkì sí àwọn Mùsùlùmí púpọ̀ nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé ọjọ́ yìí gan ni Ọlọ́run dá ẹ̀sìn Islam pé, tó sì buwọ́lùú gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí ẹ̀dá le máa tọ̀ bí Àlùkùránì ṣe sọ.

Ọ̀pọ̀ àwọn Mùsùlùmí káàkiri àgbáyé pàápàá àwọn tí kò bá lọ fún Hajj ló máa ń gba àwẹ̀ lọ́jọ́ Arafah yìí láti fi wá ojú rere Ọlọ́run.

Pípadà sí Muzdalifah

Tó bá ti di ìrọ̀lẹ́ ni wọ́n máa lọ sí Muzdalifah. Àárín Mínà àti Arafah ni Muzdalifah yìí wà.

Níbẹ̀ ni wọ́n ti máa kirun Magrib àti Ishai kí wọ́n tó sùn lálẹ́.

Nígbà tí wọ́n bá wà ní Muzdalifah yìí, wọ́n le máa ṣá òkúta tí wọ́n máa lò láti fi sọ̀kò àṣètánì kalẹ̀.

Òkúta 49 ni àpapọ̀ iye òkúta tí wọ́n nílò láti sọ̀kò àṣètánì àmọ́ wọ́n máa ń gbà wọ́n lámọ̀ràn láti ṣa 70 nítorí ó lè jábọ́. Yàtò sí Muzdalifah, ènìyàn tún le ṣa òkúta níbikíbi ní Mínà.

Ọjọ́ ọdún àti Rami

Ọjọ́ Kẹwàá oṣù Dhul-Hijjah ni wọ́n máa ń pè ní ọjọ́ al-Nahr.

Lẹ́yìn tí wọ́n bá kírun ìdájí tán ni wọ́n máa kúrò ní Muzdalifah láti padà sí Mínà. Ọjọ́ yìí ni wọ́n máa pa ẹran, tí wọ́n sì tún máa bẹ̀rẹ̀ sísọ òkò fún àṣètánì.

Gbogbo àwọn Mùsùlùmí káàkiri àgbáyé náà ló máa pa ẹran ní ọjọ́ yìí láti fi ṣayẹyẹ pé Ànọ́bí Ibrahim gba ti Ọlọ́run láti fi ọmọ rẹ, Ismail̀ rúbọ kí Ọlọ́run tó ní kó fi agbo rọ́pò ọmọ náà.

Ọdun yìí ni àwọn Yorùbá máa ń pè ní ọdún Iléyá.

Sísọ òkò fún àṣètánì

Awon to n soko fun asetani

Oríṣun àwòrán, Others

Ní ọjọ́ Kẹwàá, Kọkànlá àti Kejìlá oṣù Dhul-Hijjah - àwọn ọjọ́ mẹ́ta yìí ni sísọ òkò fún àṣètánì fi máa ń wáyé.

Àwọn òkúta yóò kò ní tóbi rárá tí àpapọ̀ wọn sì máa jẹ́ 49.

Méje ni wọ́n máa jù lọ́jọ́ àkọ́kọ́, tí wọ́n sì máa ju 21 ní ọjọ́ kejì àti ìkẹta.

Òpó Jamarat al-Aqaba ni wọ́n máa ju àwọn òkò yìí lù tí wọ́n yóò sì máa gbé Ọlọ́run tóbi tí wọ́n bá ṣe ń ju ẹyọ̀ kọ̀ọ̀kan.

Gígẹ irun

Lẹ́yìn tí pípa ẹran bá ti parí ni àwọn ọkùnrin ti le gẹ́ irun wọn nítorí láti ọjọ́ kìíní oṣù Dhul-Hijjah ni wọn kò ti ní àǹfààní láti gẹ irun títí di ọjọ́ yìí.

Bákan náà ni ànfàní tún ti wà láti bọ́ aṣọ Háràmí, kí ènìyàn pàrọ̀ sí aṣọ mìíràn tó bá wù ú láti wọ̀.

Tawaf al-Ifadha àti Saai

Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Dhul-Hijjah tó jẹ́ ọjọ́ karùn-ún tí iṣẹ́ Hajj bẹ̀rẹ̀ ni àwọn alálàájì máa padà sí Makkah láti lọ ṣe Tawaf al-Ifadha àti Saai kí iṣẹ́ Hajj wọn le pé.

Tawaf ni yíyí Kaabah ká fún ìgbà méje.

Dandan ni Tawaf al-Ifadha àti Saai lẹ́yìn tí ènìyàn bá ti sọ òkò àṣètánì tán, tó sì ti gẹ irun. Tí ìgbésẹ̀ yìí bá ti parí, ènìyàn lè ṣe ohunkóhun tó bá wù ú àmọ́ yóò padà sí abẹ́ òrùlé tí wọ́n fi wọ́n sí ní Mínà láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ tó kù.

Tawaf al-Wida

Èyí ni ìgbésẹ̀ tó lẹ́yìn nínú iṣẹ́ Hajj ṣíṣe nítorí náà ni wọ́n ṣe máa ń pè é ní Tawaf ìdágbére.

Òhun ni nǹkan tó kẹ́yìn láti ṣe tí ènìyàn bá ti fẹ́ kúrò ní Makkah tí àwọn onímọ̀ sì gbàgbọ́ pé tí ẹni tó bá ṣe Hajj kò bá ṣe é, iṣẹ́ Hajj tó ṣe kó pé.

Ẹ̀ẹmèje ni wọ́n máa ń Tawaf yìí lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n máa kírun rákà méjì, tí wọ́n sì máa mu omi Zam Zam.

Lẹ́yìn èyí ni iṣẹ́ Hajj ti parí báyìí kí Ọlọ́run gbà á ní ládá ló kù.

Fún àwọn tí kò bá ní ànfàní láti lọ fún Hajj, àwọn ọjọ́ mẹ́wàá àkọ́kọ́ nínú oṣù Dhul-Hijjah ni ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n jẹ́ ọjọ́ ńlá nínú ìgbésí ayé Mùsùlùmí, tí wọ́n sì máa ń rọ̀ wọ́n láti lékún nínú ìjọ́sìn wọn.