Sierra Leone election 2023 winner: Julius Maada Bio wọlé gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Sierra Leone

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ eleto idibo orilẹ-ede Sierra Leone ti kede arẹ Julius Maada Bio gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo aarẹ to waye ni orilẹede naa, eyi ti yoo mu ko ṣe saa keji nipo.
Alaga ajọ ECSL, Mohamed Konneh, kede ni irọlẹ ọjọ Iṣẹgun pe Bio wọle pẹlu apapọ àdá 5.17% lara ìbò ti araalu dì.
Alatako gboogi fun Bio, Samura Kamara ti ẹgbẹ oṣelu All People's Congress (APC) ni 41%.
Oriṣiriṣi awọn ẹgbẹ ati ajọ to tọpininpin eto idibo naa sọ pe ajọ eleto idibo ṣe magomago ninu kika esi ibo.
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ni eto idibo na waye.
Ofin eto idibo orilẹ-ede Sierra Leone ni pe ẹni ti yoo ba bori gbọdọ ni 55% ninu ibo ti araalu di, bi bẹẹkọ, atundi ibo yoo waye laarin oludije meji akọkọ lẹyin ọsẹ meji ti wọn kọkọ kede esi ibo.
Ó ṣeéṣe kí ẹ̀rọ ti ò n lò ma fọwọ́ sí ohun tóò fẹ́ wò yìí
Oludije mẹtala lo dije fun ipo aarẹ, lara wọn si ni Aarẹ Maada Bio to n dije fun saa keji nipo.
Awọn ololufẹ Bio ti tu si igboro, paapaa ni olu ilu, Freetown lati ṣe ajọyọ.
Igba karun-un niyii ti eto idibo n waye ni Sierra Leone lẹyin ti ogun abẹle pari nibẹ lọdun 2002.
Taa ni Julius Maada Bio?
Ọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun 1964 ni wọn bi Ọgbẹni Bio, niluu Sogbini Chiefdom, ni ẹkun Bon.
Agba oloṣelu ni Bio, to wọle sipo aarẹ lẹyin to fi ẹyin Aarẹ Ernest Bai Koroma janlẹ lọdun 2018.
Yatọ si pe o jẹ oloṣelu, ajagun fẹyinti ni Bio.
Bakan naa lo ti di awọn ipo oṣelu mu - o ti jẹ minisita fun eto iroyin, igbohunsafẹfẹ ati aṣa, ri.
O ti dari ẹka ẹnawo, ọrọ ilẹ okeere, iroyin, awọn ọ̀dọ́, ere idaraya ati lila araalu lọyẹ gẹgẹ bi olootu ijọba lọdun 1992.
Ọgbẹni Bio wa lara awọn ọmọ ogun to ja ijọba gba lọdun 1992, o si ti dari orilẹ-ede sierra Leone ri gẹgẹ bi aarẹ ologun fun oṣu meji lọdun 1996, lẹyin to dari iditẹ gbajọba.
O pada gbe ijọba pada fun alagbada.
Ọdun 2012 lo kọkọ dije fun ipo aarẹ, ṣugbọn o fidirẹmi si ọwọ Ernest Bai Koroma.
O wọle si saa akọkọ lọdun 2018 lẹyin ti atundi ibo waye.
Bio ni iyawo kan ati ọmọ mẹrin.
Lọwọlọwọ, lara awọn ipenija to n koju sierra Leone ni eto ọrọ aje, airi iṣẹ ṣe, ati ọwọn gogo ọja, to fi mọ eto abo to mẹhẹ.












