Àwọn ará ilẹ̀ Sierra Leone ń dúró de èsì ìdìbò sípò ààrẹ , aṣòfin tí wọ́n dìbò yàn

Aworan

Awọn ara orilẹede Sierra Leone n duro de esi idibo gbogboogbo to waye ni orilẹede naa.

Esi idibo naa ni ko lọ irọwọrọsẹ, ti rogbodiyan ati iwa ipa si gbode lasiko idibo naa.

Bio tilẹ jẹpẹ, eto idibo naa pe ko to bẹrẹ, ọpọ ero lo jade lati lọ dibo, ti awọn oludibo si sọ fun BBC pe awọn ni anfaani lati dibo.

Saaju ni awọn eniyan ti n woye pe o seese ki ija waye saaju idibo naa.

Ni ọsẹ to kọja ni ọkan lara awọn oludije lati ẹgbẹ alatako ni ikọ ọlọpaa yinbọn pa ọkan lara awọn alatilẹyin wọn.

Ọlọpaa fi panpẹ mu awọn ti wọn gbiyanju lati hu iwa ibajẹ lasiko eto idibo naa.

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ni orilẹede naa ni ko si otitọ ninu iroyin ọhun.

Awọn alatilẹyin ẹgbẹ oselu gboogi lorilẹede naa ni wọn ti fi ẹsun kan pe wọn n sekọlu si ara wọn.

Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan awọn eleto idibo wi pe magomago waye lasiko eto idibo naa ni Ọjọ Satide, ti wọn si ni awọn kan ji ibo ni agbegbe kan, ti wọn ko si fun awọn miran ni anfaani lati dibo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amọ Ajo eleto idibo naa ni ko si ohun to jọ bẹẹ nitori awọn sa ipa wọn lati ri pe eto idibo to munadoko lo waye nibẹ.

Bakan naa ni iroyin gbe pe awọn ọlọpaa fi panpẹ mu awọn ti wọn gbiyanju lati hu iwa ibajẹ lasiko eto idibo naa.

Ninu idibo naa ni awọn araalu ti yan aarẹ tuntun, awọn asofin tuntun, awọn kansẹlọ tuntun ninu idibo naa.

Igba karun un niyii ti wọn yoo dibo ni orilẹede naa lẹyin ogun abẹlẹ pari ni ọdun 2002.

Awọn oludije naa ni aarẹ Julius Maada Bio to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgọta lati ẹgbẹ oselu Sierra Leone People's Party (SLPP) .

Saa keji ree to n dije du ipo lẹyin to pari saa kini ọlọdun marun un.

Awọn mejila lo n baa arẹ naa du ipo, ti ọkan ninu wọn to jẹ gboogi ni Dokita Samura Kamara to jẹ ẹni ọdun mejilelaadọrin, ti ẹgbẹ oselu All People's Congress (APC).

Awọn mejeeji jọ du ipo ni ọdun 2018, ti aarẹ Bio si bori pẹlu ibo perete lẹyin ti wọn tun figagbaga ni idibo ẹlẹkeji.

Ètò ìdìbò bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu! Wo bí Sierra Leone ṣe ń ṣe ètò ìdìbò láàrìn ìbẹ̀rùbojo

Idibo Sierra Leone
Sierra Leone

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eto idibo ti bẹrẹ bayii ni orilẹede Sierra Leone nibi ti ireti wa pe o le ni eniyan miliọnu mẹta ọmọ orilẹede naa ti yoo tu jade lati lọ yan ẹti ti yoo maa tukọ adari orilẹede naa, ẹwẹ eyi n waye laarin ibẹrubojo tori iṣoro nla ti awọn ọmọ orilẹede naa n koju.

Awọn oludibo yoo dibo yan awọn aṣofin atawọn adari ni ijọba ibilẹ kọọkan.

Eyi nii yoo jẹ eto idibo ikaarun lati igba ti wọn ti pari ogun abẹle ni orilẹede naa eyi to wa sopin lọdun mọkanlelogun sẹyin.

Idibo Sierra Leone

Aṣe ibi gbogbo ni wọn ti n ko adiyẹ alẹ, lorilẹede Sierra Leone naa, ṣe ni awọn oludije ẹgbẹ oṣelu to lagbara ju ati alatako rẹ n naka alebu sira wọn.

Ni Ọjọru ọsẹ ni oludije ẹgbẹ alatako gangan, All Peoples Congress fi ẹsun kan awọn ọlọpaa pe wọn yinbọn pa ọkan lara awọn alatilẹyin oun, eyi si ni awọn ọlọpaa ni ko ri bẹẹ.

Gbogbo awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu meji to lagbara ju lo ti n fi ẹsun kan ara wọn nipa ikọlu sira ẹni.

Owurọ Oni ni Sierra Leone ṣaaju idibo
Idibo Sierra Leone

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn wo ni oludije to n le waju?

Aarẹ Maada Bio n wa atunyan fun saa ọlọdun marun mii, ẹgbẹ oṣelu rẹ ni Sierra Leone Peoples Party. O n ti ẹsẹ bọ sokoto kan naa pẹlu awọn oludije mejila mii ṣugbọn awọn onimọ gbagbọ pe alatako pataki to ni naa ni Ọmọwe Samura Kamara ti ẹgbẹ oṣelu All Peoples Congress to gba ipo keji ninu eto idibo to waye lọdun 2018.

Sibẹ awọn mejeeji naa lo kagidi bori pe onikaluku awọn lo jawe olubori idibo ọhun.

Idibo Sierra Leone

Ki ni ipenija Sierra Leone lasiko idibo yii?

Sierra Leone

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwẹ, idibo yii n waye laarin agbami ibẹru, iṣoro ọrọ aje, airiṣẹ, ọwọngogo ati ipenija irẹpọ nilu.

Ọpọlọpọ eeyan lo ti ko ounjẹ jọ sinu akaa wọn ṣaaju eto idibo yii nitori wọn bẹru pe ija le bẹ silẹ lẹyin ti wọn ti ri oniruuru ikọlukọgba laarin awọn ọlọpaa atawọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu alatako eyi to ti mu ẹmi eniyan kan lọ l’Ọjọru ọsẹ.

Sierra Leone

Oríṣun àwòrán, Getty Images