Adejare Adegoke: Láti ìgbà tí mo ti n wọ àmì ìdánimọ̀ Naijiria ni mo ti n rí àwọn àmì tó n mú inú mi dùn
Ọgbẹni Adejare Adegoke fẹran lati ma a wọ àwọ̀ idanimọ orilẹ-ede Naijiria - àwọ̀ ewé àti funfun, ti wọn n pe ni Green, white, green ni ede Gẹẹsi.
Ọgbẹni Adegoke sọ fun BBC Yoruba pe "Mr. One Nigeria" ni awọn eeyan ma n pe oun.
Ọkunrin naa to jẹ ọmọ ilu Ogbomoso nipinlẹ Oyo sọ pe nitori oun n wa ire orilẹ-ede Naijiria lo fa bi oun ṣe n mura, ati pe ojoojumọ ni oun ma n gba adura fun ire ati ilọsiwaju rẹ.
"Lati igba ti mo si ti n mura bayii ni mo ti n ri awọn ami to ma n mu inu mi dun."
O ṣalaye pe ọpọ eeyan ni oun ti yi ọkan wọn pada si rere, ti oun si fun ni ireti ọjọ ọla to dara fun Naijiria, nipasẹ bi oun ṣe ma n mura.

