Baba Wòlí, Ojo Olowere tí ìjọ CAC Òkè-Agbára tí jáde láye

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajugbaja oniwaasu ati oludasilẹ ijọ Christ Apostolic Church (CAC), Woli Micheal jo Olowere, ti ọpọ mọ si ‘’Baba Automatic’’ ti jade laye.
Olowere ni oludasilẹ ijọ CAC, Oke Agbara, ni agbegbe Ashi ni ilu Ibadan.
Awọn mọlẹbi ko i tii sọrọ nipa iku rẹ, amọ gbajugbaja adẹrinpoṣonu, Wole Arole ti fi si oju opo Instagram rẹ pe baba Wọli ọun.
Awọn aniyan jankan ṣedaro rẹ...
Iroyin ni iyawo gomina ipinlẹ Ọyọ, Tamunominini Makinde ti fi ikini ibanikẹdun ṣọwọ si awọn mọlẹbi pasitọ naa.
Iyawo gomina naa ni o ṣe apejuwe iku rẹ gẹgẹ bi eleyii to ba oun ni ojiji to si dun eniyan de ọkan.
Bakan naa ni wọn ba gbogbo ọmọlẹyin ninu Kristi
Gbajugbaja adẹrinpoṣonu, Arole loju opo Instagram rẹ ni iku Woli naa dun ohun amọ oun dupẹ pe oun jẹ anfaani ati ore-ọfẹ ipe baba naa nigba to wa ni aye.
O ni lọpọ igba ni awọn eniyan ti ma n bu ẹnu atẹ lu oun pe oun bọwọ fun awọn eniyan Ọlọrun ju bi o ṣe yẹ lọ.
Amọ o ni ifẹ ti oun ni si baba naa fi arahan nigba ti oun ṣe abẹwo si, ti o si gbadura fun oun, amọ o ni iku ti mu baba naa lọ.
Bakan naa lo ba awọn ara ninu Kristi, mọlẹbi ati ojulumọ ṣedaro Woli Olowere to doloogbe.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Tani Woli Olowere to papoda?
Ọjọ Kẹsan, Oṣu Kẹsan an ni wọn bi Woli Olowere ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bi oniwaasu, olukọni ati onimọ nipa ọrọ Olorun.
Awọn eniyan tun ṣapejuwe Woli naa gẹgẹ bi ẹni to ni ẹbun lati ṣe iṣẹ ara ati iyanu.
Baba naa jẹ ọkan lara awọn adari ijọ ni CAC ti ọpọ eniyan gboriyin fun, to si wa ni ajọṣepọ pẹlu oludasilẹ Ijọ CAC, Baba Ayọ Babalọla.
Laarin ọgọta ọdun ti baba naa fi sẹ iṣẹ iranṣẹ to si da ọpọlọpọ ijọ silẹ.
Ijọ CAC Oke-Imole, ni Agbowo ni baba naa ti bẹrẹ ni ọdun 1978.

















