Flood Alert: NEMA ṣè ìkìlọ̀ fún Ìpínlẹ̀ 14 àti agbègbè 31

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA ni o sese kí awọn ipinlẹ mẹrinla and ati agbegbe mọkanlelọgbọn ri ojo arọrọda lati ojo kẹrin si ojo kẹjọ oṣu keje.

Eyi lo jade ninu atẹjade kan ti Ibrahim Farinloye, Ọga agba fun NEMA nipinlẹ Eko buwọlu fun awọn akọroyin.

Farinloye rọ awọn ipinlẹ naa lati bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati dena ijamba nla to le mu ẹmi ati dukia lọ.

O darukọ ipinlẹ ati awọn agbegbe naa; Plateau: Langtang ati Shendam; Kano: Sumaila, Tudun Wada; Sokoto: Shagari, Goronyo ati Silame; Delta: Okwe.

Awọn ipinlẹ yooku ni Kaduna: Kachia ; Akwa Ibom: Upenekang; Adamawa: Mubi, Demsa, Song, Mayo-Belwa, Jimeta ati Yola ; Katsina: Katsina, Jibia, Kaita ati Bindawa.

Bakan naa lo darukọ ipinlẹ Kebbi : Wara, Yelwa ati Gwandu; Zamfara : Shinkafi ati Gummi. Borno: Briyel; Jigawa: Gwaram; Kwara : Jenna; Niger: Mashegu ati Kontagora.

Farinloye wa dupẹ lọwọ Ẹka ìjọba apapọ to n se iwadi lori omiyale fun bí wọn ṣe gbe iroyin naa jade.