Àwọn aráàlú fèsì sí ìgbéṣẹ́ Ààrẹ Tinubu láti gba owó ṣabuké lọ́wọ́ àwọn onímótò

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ọmọ Naijiria ti fi ero wọn han lori igbeṣẹ aarẹ Tinubu lati maa gba owo sabuke lọwọ awọn to n wa ọkọ ara wọn ni Naijiria.

Ijọba apapọ kede pe awọn fẹ maa gba ẹgbẹrun kan Naira ni ọdọọdun lọwọ awọn awakọ ni Naijiria, eleyii ti wọn pe ni Proof of ownership Certificate,POC.

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ eko ni awọn ti bẹrẹ si ni mu ofin tuntun naa ṣe ni ipinlẹ Eko.

O ni iwẹ ẹri ti wọn yoo ma gba lẹyin ti wọn ba san owo naa tan ni yoo fidi rẹ mulẹ pe ẹni naa lo ni ọkọ ti oun wa.

Ijọba fikun un pe POC naa yoo ṣafihan nọmba ọkọ naa ati awọn ohun idanimọ ti ọkọ naa.

Bakan naa ni yoo fi adirẹsi ati orukọ ẹni to ni ọkọ naa sibẹ.

Ijọba ni eyi yoo mu ki eto aabo gboro fun awọn araalu lorilẹede Naijiria, ti yoo si rọrun fun awọn alaṣẹ to n risi irinkerindo ọkọ lati le tete mọ ibi ti ọkọ ti n wa ni Naijiria.

‘’Inira yii ti pọju fun awọn araalu’’

Ọpọlọpọ awọn araalu to fesi si igbeṣẹ tuntun ijọba naa ni kii ṣe asiko yii lo yẹ ki ijọba tun gbe owo tuntun miran jade fun awọn araalu.

Lara awọn to sọrọ ni awọn araalu ṣi n koju ọwọngogo epo bẹntirol, ti inira si pọ fun awọn araalu.

Wọn tun fikun un pe ọwọngogo ounjẹ, irinna ati ina ijọba to gbe owo lori.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Amọ awọn ọmọ Naijiria kan ni ijọba Tinubu fẹ gbe eto owo ori ti wọn lo ni ipinlẹ Eko wa fun gbogbo ọmọ Naijiria.

Eleyii ti wọn ni ko tọna nitori Tinubu ko lee fi ilu Eko we awọn ilu to ku ni Naijiria.

Ninu ọrọ ti wọn, iroyin gbee pe ẹgbẹ awọn agbẹjọrọ ni Naijiria, NBA ti kede pe awọn ti gbe igbimọ dide ti yoo ṣayẹwo igbeṣẹ tuntun ti ijọba apapọ fẹ gbe lori owo sabuke lọwọ awọn ọlọkọ.

Ẹgbẹ NBA naa ni awọn yoo ṣe ayẹwọ ni finifini ti ijọba ba ni aṣẹ labẹ ofin Naijiria lati gbe iru igbeṣẹ bẹẹ.