Wo ọ̀pọ̀ àwòrán ooru àmújù tó ṣokùnfà ìjàmbá iná ní Canada, Amẹ́ríka àti ìnira tó kó bá ọ̀pọ̀ èèyàn

Ina to n jo ati awọn ti ooru mu

Oríṣun àwòrán, Reuters

Isẹlẹ ooru amuju to n waye ni awọn orilẹede bii Canada, Amẹrika ati Asia ti n se akoba fun oju ọjọ ati awọn eeyan to n gbe lagbegbe naa.

Koda, ooru amuju yii ti se okunfa ijamba ina lawon agbegbe bii oke Swiss Alps to wa ni Haute-Valais lẹba eti bode Italy nirọlẹ ana,

Bakan naa ni awọn igbo ti ara ooru amuju yii ti n kan, ti bẹrẹ si gbina nitori bi odiwọn oju ọọ se wọ 41C laarọ oni lorilẹede Greece.

Awọn osisẹ panapana si ti n lo ọkọ ofurufu ẹlikopita pẹlu awọn osisẹ to le ni igba, ti wọn n tiraka lati pa ina ọhun.

Koda, se lawọn eeyan orilẹede naa ji lonii, ti wọn si ri pe isẹlẹ iajmba ina mẹta lo fire laarin ọjọ meji nilu naa.

Awọn eeyan ti ooru mu

Oríṣun àwòrán, EPA

Koda, isẹlẹ ooru amuju yii si lo n ko inira nla bawọn eeyan ati ẹranko lorilẹede Spain pẹlu, ti ọpọ eeyan nilẹ Yuroopu si bọ ara silẹ lati gba atẹgun.

Ọrọ yii ko si yọ China silẹ, to fi mọ Amẹrika, ti ina alagbara kan si n jo lati ọjọ melo kan ni ipinlẹ Califorlia.

O si ti le ni eeka ilẹ ẹgbẹrun mẹjọ ti ina naa jo nipinlẹ naa, to fo mọ awọn igi nla nla to wa ninu igbo.

Canada naa ti gba alejo ina yii, ti isẹlẹ naa si ti to ẹẹdẹgbẹrun ina to n jo kaakiri lọjọ Aje, ti ẹgbẹta ninu isẹlẹ ina yii si ti kọja agbara awọn osisẹ panapana to fẹ kawọ rẹ ko.

BBC wa se akojọpọ aworan nipa awọn isẹlẹ ijamba ina to wa lati ara ooru amuju to n mu lawọn orilẹede ti ọrọ naa kan.

Bakan naa ni awọn aworan yii n sọ nipa akoba ti ooru amuju yii n ni lori awọn eeyan ati ẹranko to wa lawọn orilẹede yi isẹlẹ yii ti n waye.

Ooru to n bu jade labẹ ilẹ, to se okunfa ina

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ina to su yọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ẹranko gan mọ inira ooru amuju yii lara, se ni wọn n wa ibi fori pam si
Se fila ti eeyan gbe sinu omi, to tutu le da ọwọja ooru amuju duro bi?
Ilu kan ree ti oorun ti bẹju kẹ
Ọkunrin kan ree to gbe ori sabẹ omi tori ọsẹ ooru amuju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obinrin kan ree to ko sinu odo, to si tun da aburada bori tori oorun. Eyi ko wa pa ni lẹrin bi?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn panapana ko sinmi lati bomi pana isẹlẹ ijamba ina to n waye tori ooru amuju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ori obinrin yii n gbona gidigidi lo se gbe ori sabẹ omi tori ooru amuju

Oríṣun àwòrán, EPA

Ina alagbara to sẹyọ tori ooru amuju, jo ile nla kanlẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aayan n lọ lati pana to n sẹ yọ tori ooru amuju

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn eeyan bọrs silẹ lati gba atẹkun

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọwọja ina yii le to bẹẹ, baalu Ẹlikoputa ni wọn n lo lati pa ina ọhun

Oríṣun àwòrán, Reuters