Men who trained on house chores: Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú kí ọkùnrin máa ṣiṣẹ́ ilé
Ni ilẹ Yoruba, asa tiwa ni pe obinrin nikan lo gbọdọ maa kọ bi a ti n se isẹ ile, ti ọkunrin yoo si maa wa ohun jijẹ lọ sita fun idile rẹ.
Amọ lode oni, aye ti yi, igba si ti yi pada pẹlẹ, ti ọpọ eeyan lagbaye si n ba aye yi pẹlu.
Idi ni pe awọn ọkunrin naa ti n sisẹ ile gẹgẹ bii awọn obinrin, tawọn obinrin naa si ti n sisẹ oojọ lati wa ounjẹ sinu ile, gẹgẹ bii awọn ọkunrin.
- Tinubu yóhùn padà lórí fífún àwọn tálákà ní ₦8,000, kéde ìgbésẹ̀ tuntun
- Ààrẹ Tinubu bá àwọn òbí ọmọ ọdún méjì tí àsìta ìbọn pa ní Delta kẹ́dùn
- Bí ọwọ́ ṣe tẹ ẹni ọdún 32 tó fún ìyá rẹ̀ lọ́run pa nípinlẹ̀ Ogun
- Awọn ọmọ Nàìjíríà fẹ́ràn láti gba adigunjalè mọ́ra ju àwa -transgender- táa ń múra bí obìnrin lọ - Jay Boogie
- Iye -owó nǹkán l'ọ́jà tún lọ sókè pẹ̀lú ìdá 22.79% - Àjọ Aṣèṣirò NBS
Amọ awọn ọkunrin kan ree lorilẹede Uganda, ti wọn mu isẹ ile yii lọkunkundun, ti wọn si jade lọ sita lati lọ kọ bi yoo se rọrun fun wọn lati sisẹ ile.
Ajọ kan si lo wa, ti orukọ rẹ n jẹ ajọ JESE, eyi to n parọwa si awọn ọkunrin naa lorilẹede Uganda lati wa kọ bii eeyan se n sisẹ ile.
Ajọ yii si lo n polongo ibaradọgba laarin akọ ati abo, eyi to tumọ si pe ibi ko ju ibi, ba se bi ẹru, ohun naa la bi ọmọ.
Ọpọ ọkunrin lo ti dara pọ mọ ajọ naa, lara ohun ti wọn si n kọ nibẹ ni bi a ti n se ọbẹ, se ounjẹ, tun inu ile se, pọn omi sile ati setọju ẹbi wọn.
Koda, a ri awọn ọkunrin yii, ti wọn se ounjẹ fawọn aya wọn lati jẹ, ti inu awọn obinrin naa si dun.
- Mọ̀ ń tọrọ àgbàdo ni kí n lè rí oúnjẹ òòjọ́ jẹ - Àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ ìrírí wọn lásìkò -subsidy- àti ọ̀wọ́ngógó yìí
- Wo ọ̀pọ̀ àwòrán ooru àmújù tó ṣokùnfà ìjàmbá iná ní Canada, Amẹ́ríka àti ìnira tó kó bá ọ̀pọ̀ èèyàn
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Anthrax to ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ Nàìjíríà
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí iléẹjọ́ ṣe tú Pásítọ̀ ‘Miracle Babies' tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó ń pèsè oyún àbàadì sílẹ̀
- Ọlọ́pàá Eko bá òkú ọmọge nínú ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀, ìwádìí bẹ̀rẹ̀
Lasiko ti wọn n ba akọroyin BBC sọrọ, awọn obinrin naa ni igbesẹ ki awọn ọkunrin maa sisẹ ile dara pupọ nitori yoo bu iyi pupọ fun wọn ninu ẹbi wọn.
Bakan naa ni igbesẹ naa yoo tun fawọn aya wọn laaye lati sisẹ owo miran dipo ki wọn jẹ iyawo ninu ile lasan.