Mọ̀ ń tọrọ àgbàdo ni kí n lè rí oúnjẹ òòjọ́ jẹ - Àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ ìrírí wọn lásìkò "subsidy" àti ọ̀wọ́ngógó yìí

Asiko ọwọngogo to gbode ti mu ki ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria maa wa ọna lati ri ounjẹ oojọ wọn jẹ.
Awọn ti ko ri aje jẹun ni awujọ ni ọwọngogo naa n han ni eemo nitori aisi owo to gbode kan.
Orilẹede Naijiria jẹ ọkan gboogi ninu awọn orilẹede ni ilẹ Afrika ti ọrọ aje wọn gbooro julọ amọ ọwọngogo ile ati ounjẹ ko mu ki igbe aye awọn eniyan rọrun.
Eyi ni iṣoro ti awọn eniyan n koju ki aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu tun wa yọ owo iranwọ epo bẹntiroo, to si mu ki iṣoro aisi owo buru sii.
Ninu ọrọ rẹ, arabinrin Hasiya Uba to n gbe ni ipinlẹ Kano ni ariwa orilẹede Naijiria ni iṣẹ ti oun wa n ṣe bayii ni lati ji ni aarọ kutukutu ki oun si maa ya ojule si oju le lati maa tọrọ ounjẹ aarọ.
O ni lati bi ọdun kan bayii ni oun ati aburo oun ti n pese ounjẹ aarọ, ọsan ati alẹ fun awọn mọlẹbi oun, ti wọn jẹ mẹfa.
‘’Kii ṣe iru igbe aye ti a fẹ leleyii, amọ ohun gbogbo to yipada lo mu ki a di atọrọ jẹ’’

‘’Kii se iru igbeaye ti a fẹ leleyii, kii si se iru igbe aye ti a n gbe tẹlẹ niyii, amọ ohun gbogbo to yipada lo mu ki a di atọrọjẹ.’’
Baba wa jẹ ẹni to maa n sẹ aṣọ ta ni ọja Kantin Kwari, ọja naa to doju bole, ti ko si ọna miran fun wa lati ri ounjẹ jẹ.
Nitori naa ni emi ati ẹgbọn mi se n jade lọ lati ojule de ojule lati lọ tọrọ ounjẹ, ti a o si mu wa si ile fun awọn iyoku lati jẹun.
Arabinrin naa ni ko si ẹnikankan ninu awọn mọlẹbi wọn to n lọ si ileẹkọ mọ nitori ounjẹ oojọ ni wọn n wa bayii.
Awọn mọlẹbi miran bii Hasiya pọ ni Naijiria ti iriri wọn yoo si jẹ iyalẹnu fun awọn eniyan.
Ẹlomiran to sọ iriri rẹ lori redio ni Kano ni awọn eniyan ma n tọrọ agbado abi ki wọn ya agbado lọwọ awọn ara agbegbe wọn ki wọn fi le se Tuwo, ti wọn yoo jẹ nitori ko si owo.
Iye ti wọn n ta awọn ounjẹ di ọwọngogo, ti ko si rọlẹ

Laipẹ yii ni awọn oniburẹdi kede pe awọn yoo fi owo kun iye ti wọn n ta burẹdi kaakiri orilẹede Naijiria.
Ninu atẹjade ijọba laipẹ yii, iṣuwọn ọwọngogo ni Naijiria ti goke de 22.79% lati 22.41% to wa ni Osu Karun un.
Eyi tumọ si pe iye ti wọn n ta ọja n goke sii lai duro lati bii oṣu mẹfa ṣẹyin.
Ọwọngogo naa ko ṣẹyin iye ti wọn n ta ounjẹ to n goke sii, iye owo ile, omi, owo ina ati iye ti wọn n ta epo bẹntiroo.












