Àlàyé rèé lórí ìdí tí iléẹjọ́ ṣe tú Pásítọ̀ ‘Miracle Babies' tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó ń pèsè oyún àbàadì sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileęjọ ti tun Pasitọ kan orilẹede Kenya tí wọn ní o n pese oyun aramọnda fun awọn eeyan silẹ.
Wọn tun Gilbert Deya silẹ lori ẹsun karakata ọmọ ti wọn fi kannitori ko si ẹri to to niwaju ileẹjọ.
Ileęjọ ni olupẹjọ kuna lati pe ẹri pe otitọ ni pe Deya ji ọmọ marun un gbe logun ọdun sẹyin.
Wọn fẹsun kan pe o gbe awọn ọmọ naa fun awọn obìnrin ti ko ri ọmọ bi.
Wọn fi Pasitọ soko pada lati UK lọdun 2017 lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti igbęjọ naa bẹrẹ.
Olupẹjọ ni awọn ile igbẹbi to wa ni Kenya, ni wọn ti maa n gbe ọmọ tuntun wa fawọn oloyun abaadi to wa nile ijọsin pasitọ yii ni London
Saaju ni ọrọ Deya jẹyọ nigba to n se isakoso ile ijọsin kan lorilẹede London ninu iwadi kan tí BBC ṣe lọdun 2004.
Won maa n sọ fun awọn obinrin to ipenija ọmọ lati lọ ile ìjọsin Gilbert Deya Ministries ni Peckham nitori wọn yoo ri ọmọ ìyanu nibẹ.
Ṣugbọn awọn ọmọ yii ni wọn maa n gbe wa lati ile agbẹbi ni Nairobi lorilẹede Kenya.
Olùpẹjọ ni awọn ọmọ wọnyi ni wọn jigbe lati ọdọ awọn idile kan ni Kenya.
Deya pada gbera lọ si Scotland, ti ọwọ Ọlọpaa si tẹ ni Edinburgh lọdun 2006 lẹyin ti orilẹede Kenya kesi ajọ agbaye.
Ninu idajọ rẹ lọjọ Aje, Onidajọ Robinson Ondieki ni olùpẹjọ ko ni ẹri to to lati fẹsun kan Pasitọ naa.
Lasiko to n sọrọ niwaju ileẹjọ níbi tí awọn ololufẹ rẹ ti n kan sara si.
Deya ni oun ti darijin gbogbo eeyan ti wọn fẹ ki oun lọ sẹwọn.
"Loni ileęjọ ti da mi laare, ọrọ ti tabuku si mi pe mo n jí ọmọ.
"Inu mi dun pe mo ti gba ominira bayii. Bayii ma tẹsiwaju ninu isẹ ti Jesu ran mi lorilẹ Aye.
Deya ni o sese ki oun pada si UK.
Lọdun 2011, Mary Deya, Iyawo Deya tẹlẹ rí ẹwọn he lẹyin ti wọn fẹsun gbọmọgbọmọ kan pe o ji ọmọ kan ni ile wosan kan ni Nairobi to si parọ pe oun ni oun bi ọmọ naa.
Ta ni Gilbert Deya?
Gilbert Deya gbera kuro orilẹede Kenya lọ London ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
O da ile ìjọsin Gilbert Deya Ministries silẹ, to si ni ẹka ni ilẹ Afrika ati Asian.
Ọpọ lo mọ fun bi o ṣe ma waasu kíkankíkan.
Deya ni Olusọ Aguntan kan ni Amẹrika ni o sọ oun di Arch Bíṣọọbu lọdun 1992,
Wọn fẹsun kan Deya pe o ji ọmọ marun un laarin ọdun 1999 si 2004, to si foju ba ile ẹjọ ni Nairobi to jẹ olu ilu Kenya















