Tobi ní òun kò ní jẹ́ asáré ojú títì lásán, mo sì ń tì í lẹ́yìn - Alàgbà Amusan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn obi Oluwatobiloba Amusan, to jẹ elere ori ọdan ọmọ Naijiria, ti n jo yagini yojo pẹlu bi ọmọ wọn ṣe gbegba oroke ninu idije igi fifo 100m hurdles.
Nibi idije Commonwealth Games ni akikanju obinrin yii ti fi itan lelẹ gẹgẹ bi ẹni to yara sa ere naa julọ ni isọri awọn obinrin.
O fi akoko tuntun 12.30 lelẹ lati fi gba ami ẹyẹ wura lorukọ Naijiria lowurọ ọjọ Aiku.
Ṣaaju lo ti kọkọ gba ami ẹyẹ rẹ akọkọ nibi abala to kangun si aṣekagba idije elere igi fifo 100 metres hurdles lọjọ Aiku.
Awọn obi rẹ, arakunrin ati arabirin Amusan sọ fun BBC pe awọn ko ti gbagbe ayọ ati idunnu tawọn mọ nigba ti Tobi gba ami ẹyẹ wura.
Bakan naa lo si tun fi itan lelẹ nibi idije World Athletics Championships to waye ni Eugen USA.
Nibẹ lo ti fi itan lelẹ gẹgẹ bi ọmọ Naijria akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ wura nibi idije naa.
Baba Tobi sọ iriri rẹ lalẹ ọjọ ti Tobi gba ami ẹyẹ nibi idije World Chamìonship.
O sọ fun BBC pe oun ko sun daada lalẹ naa nitori pe oun fẹ wo Tobi lasiko ti yoo sare lori amohunmaworan.
‘Ayọ mi kun nigba ti ọmọ mi soriire’
Baba Amusan tẹsiwaju pe ''Nigba ti Tobi kopa nibi idije World Championship, mo sọ pe mo gbọdọ darun mọju lati wo isesi rẹ lori ọdan.
Oorun diẹ bẹrẹ si ni kun mi nitori akoko wa yatọ si ti ilu to ti n kopa nibi idije naa.
Gẹgẹ bi obi, bi ọmọ rẹ ba ṣe oriire, idunnu rẹ ko ni lopin, a kọrin, a jo, a fọpẹ fun Ọlọrun. Inu wa dun pupọ''
Kii se ọjọ ti eeyan ba gun, lo n kan ọrun, lẹyin igbesẹ akọkọ, mo ti n sọ fun awn ohun to yẹ ko se atawọn ohun ti ko yẹ ko se.
Koda, Tobi sọ fun mi pe laelae, oun ko ni jẹ asare oju titi lasan, lati igba naa ni mo ti n se atilẹyin fun.
Mo si nigbagbọ ninu rẹ pe lọjọ kan, yoo di ohun eelo to se iyebiye lagbo ere idaraya.
Lootọ ni ala mi pada wa sẹ lori rẹ, eyi to dun mọ mi ninu, ogo si ni fun Oluwa nitori kii se mimọọse wa.
O fikun pe oun ko mọ pe iru ọjọ bayii yoo waye, ti ogo Tobi yoo tan bi ti irawọ.
Baba Tobi sọ pe kii ṣe mimọ ṣe awọn bi kii ṣe pe Ọlọrun lo gbogo fun ọmọ awọn.
















