Israel dáwọ́ ìkọlù sí Gaza dúró lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta

Awọn oluwọde ọmọ Gaza lasiko isinku eeyan wọn kan to padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency via Getty

Idawọduro ikọlu awọn ọmọ ogun Israel si awọn ọmọ ogun Palestine waye mojumọ oni lẹyin ikọlu ọjọ mẹta.

Koda bawọn kan ṣi ṣe n yinbọn diẹ diẹ saaju ati lẹyin gbedeke idawọduro yi ko ni ko ma pada waye.

Orileede Egypt lo jẹ bi apẹtusaawọ ti yoo ba wọn jiroro papọ.

O kere tan eeyan mẹrinlelogoji lo ti padanu ẹmi wọn ninu ikọlu yi to waye lẹyin ọjọ mọkanla to waye kẹyin ni oṣu kaarun ọdun 2021.

Amẹrika ati ajọ isọkan agbaye ti rọ awọn olori nigun mejeeji pe ki wọn tẹsiwaju lati maa tẹle idawọduro ija to wa nilẹ yi.

Ninu atẹjade to fi sita ,aarẹ Amẹrika, Joe Biden gboriyin fun idawọduro ija yii.

O si kesi gbogbo awọn ti ọrọ kan lati ''tẹle ni tododo ki wọn si ri pe nkan eelo ribi wọle sọdọ awọn eeyan Gaza.''

Bakan naa lo ni ki wọn ṣe iwadii iṣẹlẹ ifarapa awọn araalu lai fi akoko ṣofo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Egypt lo n petu saawọ yii, to si ti ṣaaju ṣe iru iṣẹ yi ninu ikọlu laarin Israel ati Gaza to waye tẹlẹ

Amọ bi wọn ṣe fẹsẹ idawọduro ija duro lọjọ Aiku,ileeṣẹ ologun Israel sọ pe awọn n yin ado oloro lu awọn aaye tawọn ọmọ ogun Palestinian Islamic Jihad wa tori pe wọn yin ado lu awọn naa.

Bakan naa awọn ileeṣẹ iroyin Israel jabọ pe awọn ọmọ ogun Palestine yin ado oloro ni iṣẹju diẹ lẹyin gbedeke idawọduro naa.

Sugbọn ikọlu mii ko waye nigba ti ilẹ yoo fi ṣu.

Ikọlu to n waye yi bẹrẹ lẹyin ti Israel ṣe ikọlu sawọn agbegbe kan ni Gaza eyi ti awọn ọmọ ogun rẹ sọ pe wọn ṣe ni idahun si idunkoko awọn ajijagbara nibẹ.

Nigba ti yoo fi to irọlẹ ọjọ Aiku, awọn alaṣẹ Palestine sọ pe ọmọde mẹẹdogun lo padanu ẹmi wọn ninu awọn mẹrinlelogoji to ku ninu ikọlu ọhun.

Bẹẹ naa ni ileeṣẹ ilera Gaza dẹbi ikọlu naa ru idunkoko Israeli to mu ki awọn ọmọ Palestine ku tawọn to le ni ọọdunrun si farapa.

Israel naa naka abuku si ikọ PIJ pe awọn ni wọn ṣeṣi fa iku awọn to wa ni Gaza nipa pe ikọ yi yin ado oloro to ba awọn aimọye ọmọde ni Jabalia.

Palestine pàdánù èèyàn 32 bí àkọ̀tun ìkọlù ṣe bẹ̀rẹ̀ láàrin rẹ̀ àti Israel
Ado oloro to bu ni Gaza

Ikọ ọmọ ogun orilẹede Israel ti pa asaaju ajijagbara to tobi sikeji ninu ikọ to n jija Jihad fawọn mususlumi to wa nilẹ Palestine.

Ọmọde mẹfa atawọn ologun ofurufu, to fi mọ Khaled Mansour ati tayseer Jabari, lo wa lara eeyan mejilelọgbọn to ti ba ikọlu naa lọ lati ilẹ Palestine.

O le ni ẹgbẹta ado iku ti ikọ ologun Palestine ti yin mọ Israel lati ọjọ Ẹti, osisẹ kan ni Israel lo fidi eyi mulẹ.

Isreal ni oun bẹrẹ akọtun ikọlu naa nitori idunkoko ẹsẹkẹsẹ ti ikọ ajijagbara PIJ n se.

Àkọlé fídíò, Israel-Gaza: Emergency services respond after air strike hits building in Gaza

Akọtun ikọlu yii lo lagbara pupọ aarin Israel ati Gaza lẹyin ikọlu ọlọjọ mọkanla ti wọn se kẹyin losu Karun ọdun 2021.

Awọn ologun ilẹ Isreal ti wa n sekilọ pe akọtun ikọlu naa, ti wọn pe ni Dawn, to tunmọ si ibẹrẹ, le gba wọn to ọsẹ kan gbako.

Ileesẹ eto ilera lagbegba Gaza ti wa di ẹbi isẹlẹ yii ru bi Isreal se n wọna lati gbẹmi awọn ọmọ ilẹ Palestine ati ọpọ eeyan to farapa.

Amọ Isreal ti wa fi ẹsun kan ọmọ ogun Palestine pe awọn lo se okunfa ọpọ iku awọn eeyan naa nitori asita ado iku ti wọn yin lọjọ Satide lo pa ọpọ ọmọde nilu Jabalia to wa ni agbegbe Gaza.