Shireen Abu Aqla: Ìtàn àkọ̀ròyìn Al Jazeera tí wón pa ní Israel rè é

Shireen Abu Aqla

Oríṣun àwòrán, Others

Ìtàn àkọ̀ròyìn Al Jazeera tí wón pa ní Israel rè é

Ọdun marundinlogun ni oniroyin naa fi jẹ gbajugbaja ti wọn mọ fun iṣẹ takuntakun loju ogun gẹgẹ bi akọroyin.

Gbajugbaja oniroyin ọmọ ilẹ Palestine, Shiren Abu Aqla ni wọn ti pa lasiko to n ṣiṣẹ gẹgẹ bi oniroyin fun ileeṣẹ iroyin Aljazeera.

Abu Aqla lo ṣiṣẹ oniroyin ni agbegbe West Bank ni ibi ti ija ti ma n waye laarin Palestine ati Israel.

Ileeṣẹ Al Jazeera ni Qatar ni awọn ikọ ọmọogun ilẹ Israel lo pa oṣiṣẹ wọn lai ni idi.

Bakan naa ni ileeṣẹ eto ilera ni Palestine ni Abu Aqla ku lasiko to n kọ Iroyin nipa bi Ilẹ Israel ṣe ṣekọlu si ibugbe ogunlende ni Jenin.

Atẹjade naa ni ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni wọn yinbọn fun arabinrin naa ni ori lati ọọkan.

Bio tilẹ jẹ pe o wọ ibori ati ewu to sọ wi pe akọroyin ni, wọn yinbọn lu u ni ori.

Amọ Olootu Ilẹ Israel ni oṣeeṣe ko jẹ agbẹbọn ọmọ ilẹ Palestine lo yinbọn lu u lasiko ti wọn doju ibọn kọ ikọ Ologun ilẹ Israel.

Àkọlé fídíò, Segalink:ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró bẹ́ẹ̀ wọn kò ni agbẹnusọ

Tani Akọroyin Shireen Abu Aqla ti wọn yinbọn pa?

Ọdun 1971 ni wọn bi Shireen Abu Aqla ni Jerusalem, to si lọ si ileẹ̀kọ́ Rosary Sisters High school ni agbegbe Beit Hanina, Jerusalem.

O kọkọ lọ si fasiti Jordan University of Science and Technology lati lo kọ imọ nipa Art.

Lẹyin naa lo kẹkọ gboye Bachelor's degree ni imọ iroyin lati fasiti Yarmouk University ni Jordan.

O ṣiṣẹ pẹlu ọpọlọpọ ileeṣẹ iroyin ti ilẹ Palestine to fi mọ ''Voice of Palestine ati Amman TV.

Ọdun 1997 lo darapọ mọ Aljazeera lẹyin ọdun kan ti wọn da silẹ, to si jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ akọkọ ni ileeṣẹ naa.

Ọdun marundinlogun ni oniroyin naa fi jẹ gbajugbaja ti wọn mọ fun iṣẹ takuntakun loju ogun gẹgẹ bi akọroyin.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'