2023 Presidency: Iṣẹ́ Ọlọ́run tí mo gbé dáni kọjá ipò Ààrẹ Nàìjíríà – Bíṣọ̀ọ̀bù David Oyedepo

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Bí oníwá àti ẹlẹ́yìn ṣe ti ń kéde láti fi èròńgbà àti ìpinu wọn hàn láti díje sípò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, adarí ìjọ Living Faith Church Worldwide tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Winners Chapel, Bíṣọ̀ọ̀bù David Oyedepo ní gbígbégbá òṣèlú fún òun ní àsìkò yìí dàbí kí ènìyàn máa padà sẹ́yìn.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi àpérò kan, Oyedepo ní ó ti jù fún òun láti gbégbá tàbí máa díje du ipò Ààrẹ fún òun lásìkò yìí.
Bákan náà ló rọ àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ láti ní ìfarajìn sí sínsin Ọlọ́run bó ṣe tọ́ kí Ọlọ́run le máa tó wọn ní gbogbo ìgbésí ayé wọn.
- Ẹbí kan pàdánù ọmọ mẹsan-án nínú èèyàn 435 tí omiyalé pa
- Irọ́ ni pé Bola Tinubu fẹ́ kúrò ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Agbẹnusọ Aṣíwájú
- Èsì ìdánwò UTME abala àkọ́kọ́ yóò jáde lọ́sẹ̀ yìí- Àjọ JAMB
- Ẹkún tún sọ ní Zamfara, àwọn agbébọn pa èèyàn 48
- Bí Jibrin ṣe kúrò ní ẹgbẹ̀ òṣèlú APC kò níi ṣe pẹ̀lú Bola Tinubu- Agbẹnusọ ìpolongo
- Kí nìdí táwọn iléeṣẹ́ bàlúù ní Nàìjíríà ṣe fẹ́ wọ́gilé ìrìnnà òfúrufú ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Ajé?
- Wo ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní "ọ̀nà ikú" tí àwọn ènìyàn ṣì ń ṣe ìrìnàjò lórí rẹ̀ síbẹ̀
- Ẹ gba ìpínlẹ̀ Eko kúrò lọ́wọ́ àwọn àjòjì - Atiku sí Bode George
- Mo dúpẹ́ ó! Mo bẹ́ orí fún gbogbo àgbẹ̀ àti olùfọkànsìn tó ń dáwó fọ́ọ̀mù Ààrẹ fún mi àmọ́ ẹ jẹ́ n lo óògùn ara mi - Emefiele
- Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn tó gbalẹ̀ kan l'Ekiti, a ti f'òfin bọ ọ̀rọ̀ Pasito Ade Abraham - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Ekiti
- Ṣé ó ṣeéṣe kí ẹgbẹ́ ASUU fi òpín sí ìyànṣẹ́lódì rẹ̀ lọ́jọ́ Aje?
- Torí oge ṣíṣe, wo obìnrin tó ṣe ìrìbọmi omi tútù àmọ́ tó já sí ikú fún u
Oyedepo ní òun ní ìgbàgbọ́ nínú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni òun ṣì fi wà ní orílẹ̀ èdè yìí títí di àsìkò yìí tí òun sì ń fi gbogbo ìgbà àti tinútinú òun gbàdúrà pé kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dára ju bó ṣe wà yìí lọ.
Ó fi kun pé bí àwọn kan bá ń pe òun láti wá ṣe Ààrẹ Nàìjíríà túnmọ̀ sí wí pé òun ń padà sẹ́yìn ni nítorí òun tí Ọlọ́run pe òun fún jẹ́ láti sin gbogbo àgbáyé.
Ó tẹ̀síwájú wí pé láti ọdún 1984 ni òun ti rí ìpè Ọlọ́run láti sìn-ín .
"Kódà èṣù gan náà ms wí pé kò sí wí pé kò sí bí ènìyàn ṣe máa jókòó ti Ọlọ́run tó ma wá jogun òfo."
"Láti ìgbà tí mo ti wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni mo ti máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé mi ò fẹ́ fi ìlú kan sílẹ̀ bí mo ṣe ba."
Ó ní iṣẹ́ Ọlọ́run kò sú òun láti ọdún 1976 tí òun ti bá Ọlọ́run pàdé.


















