2023 Elections: Gọngọ sọ! Adarí ìpolongo ètò ìdìbò Tinubu fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, @Jibrin
Kii ṣe nitori pe Senato Bola Tinubu n dije dupo aarẹ Naijiria ni Jibrin ṣe kuro ninu égbẹ APC- Agbenuso
Ni kete ti Alhaji Abdulmumin Jibrin to jẹ oludari agba ipolongo ati ifitonileti ajọ Bola Tinubu Campaign Organisation ṣe kọwe fipo reẹ silẹ ni oriṣii risii iroyin ti n jade lori ayelujar.
Bi awon kan ṣe n sọ pe ko wa tan bayii ni awọn mii n beere pe kini igbese Jibrin yii tumọ si fun Oloye Ahmed Bola Tinubu to ti kede pe oun n dije dupo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ APC.
- A kọ̀ láti yí ọkàn wà padà lórí ìpinnu Yorùbá Nation- Ilana Omo Oodua
- Òní ni ọjọ́ mẹ́jọ ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi ni ìlú Oyo
- Mi o rí òṣèrékùnrin tí kìí yan àlè lẹ́yìn ìyàwó wọn- Iyabo Ojo
- Ẹ gba ìpínlẹ̀ Eko kúrò lọ́wọ́ àwọn àjòjì - Atiku sí Bode George
- Torí oge ṣíṣe, wo obìnrin tó ṣe ìrìbọmi omi tútù àmọ́ tó já sí ikú fún u
- Mo dúpẹ́ ó! Mo bẹ́ orí fún gbogbo àgbẹ̀ àti olùfọkànsìn tó ń dáwó fọ́ọ̀mù Ààrẹ fún mi àmọ́ ẹ jẹ́ n lo óògùn ara mi - Emefiele
Ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria ni pe ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ to n kopa gidi ninu ajọ Bola Tinubu Campaign Organisation ti ba NAN sórọ.
Wọn ni eekan ni ti ko fẹ darukọ rẹ ti sọ pe igbesẹ Jibrin yii ko ni nkankna se pelu idije dupo Bola Tinubu.
Ati pe ikọwe fipo silẹ Jibrin yii ko da ohunkohun duro ninu iṣẹ Tiunubu Support Group Management Council eyi to jẹ igbiomọ agba awọn alatilẹyin fun Oloye Bola Tinubu.
O ni pe igbesẹ Jibrin yii ni i ṣe pẹlu iṣẹlẹ abẹnu to n ṣẹlẹ lẹgbẹ oselu APC ni ipinle Kano ni Oke Oya.
Wọn ni pe igun ti o kuna nile ẹjọ lọjọ Eti ni Kano ni eyi ti ile ẹ\jọ giga Naijiria ti wọgile ẹjọ kotẹmilọrun ti ẹka G7 APC ti Shekarau pe ni Jibrin jẹ ara kan ninu wọn.
Eyi si ṣeeṣe ko ṣokunfa idi ti Jibrin fi kọwe fipo silẹ.
Adarí àpapọ̀ fún ètò ìpolongo àwọn alátìlẹyìn Tinubu láti díje sípò Ààrẹ Nàìjíríà, Abdulmumin Jibrin ti fi ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressivess Congress, APC sílẹ̀.
Jibrin tó kéde ìpinu rẹ̀ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta lórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter rẹ̀ ní òun yóò kéde ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn tí òun yóò darapọ̀ mọ́ láìpẹ́ ọjọ́.
Ó ní òun ti sa gbogbo ipá òun fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC, àsìkò sì ti tó fún òun láti tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò òṣèlú.
- Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn tó gbalẹ̀ kan l'Ekiti, a ti f'òfin bọ ọ̀rọ̀ Pasito Ade Abraham - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Ekiti
- Ṣé ó ṣeéṣe kí ẹgbẹ́ ASUU fi òpín sí ìyànṣẹ́lódì rẹ̀ lọ́jọ́ Aje?
- Bíbéli mi ló sọ pé kí n fẹ́ ìyàwó omidan mẹ́rin, kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀- Pásítọ̀
- Ikú d'óró! Wole Adetiran tó kọ orin àdákọ àgùnbánirọ̀ Naijiria 'NYSC Anthem' ti jáde láyé
- Àjọ̀ JAMB kéde àwọn nkan tí akẹ́kọ̀ọ́ kò gbọdọ̀ mú wọ yààrá ìdánwò fún UTME 2022
- Wọ́n tún ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó tí Abacha jí kó ní UK
- Òkú obìnrin yìí kan ìlẹ̀kùn pósí gbà-gbà-gbà pé òun ò kú lọ́jọ́ ìsìnkú rẹ̀! Kàyéfì tuntun
Gọngọ sọ! Adarí ìpolongo ètò ìdìbò Tinubu fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀
Ó fi kun wí pé láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún ni òun yóò fi ẹgbẹ́ tuntun tí òun ń lọ léde.
Bákan náà ló ni òun yóò fi ọ̀rọ̀ léde láìpẹ́ ọjọ́.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Jibrin kò sọ ìdí pàtó tí ó fi fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ lásìkò yìí pàápàá bí ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ náà ṣe ń kan ilẹ̀kùn dẹ́dẹ́.
Ìbéèrè tó gbẹnu àwọn ènìyàn báyìí ni pé kí ló le mú Jibrin ju ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ bí àmukù ọsàn báyìí pàápàá bó ṣe jẹ́ pé òun ló ti ń gba iwájú lórí ìpolongo ipò Ààrẹ fún Tinubu tó jẹ́ adarí àpaps fún ẹgbẹ́ òṣèlú Apc.





















