Alaafin's burial: Òní ni ọjọ́ mẹ́jọ ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi ni ìlú Oyo

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, @Alaafin

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

A-gbọ́-'sá!-sá!!'-má-sàá.

Babaa Babátúndé,

A-gbọ́-'yà!-yà!!'-má-yà.

Àtàndá, babaa Kúdí

Tíí gbọ́ kurúù má mira.

Láyíwọlá, ọba lọmọọ Láwọin.

Kábíèsí Aláàfin.

Àjẹ́-kùnrin

Abẹ-lórí-eékán;

Àjẹ́-kùnrin

A-bi-làbẹlàbẹ-ìjà-layà.

Diẹ lara oriki Oba Lamidi Adeyemi to darapọ mọ awọn Alaseku ree.

Ojo ketalelogun, osu kẹrin, ọdun 2022 ni Oba Atanda Olayiwola Adeyemi waja.Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀

Leyin ti ara Oba Lamidi Adeyemi wo kaa ile tan ni wọn ṣe Orò Ije fun Alaafin Oyo to jọba fun odun mejilelaadota ki o to terigbaṣọ.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua
Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, @Alaafin

Ojọ Abamẹta Oni, ọgbọn ọjọ, oṣu kérin ọdun 2022 ni wọn yoo ṣeto ayẹyẹ ọjọ mẹjọ iranti ipapoda Oba Lamidi Adeyemi ni Oyo.

Aago mọkanla ni gbogbo eto yoo bẹrẹ ni Aafin Oyo.

Yoruba ni ori ti yoo dade, ko ni ṣe alai dade, ọrun ti yoo si lo ejigbara ilẹkẹ, ko ni ṣalai lo ó, ibadi ti yoo lo mọsaji, aṣọ ọba to jinna koro koro, ko kuku ni ṣe alai lo.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Bẹẹ ni ọrọ Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta rí,ẹni ti ori gbe de ipo awọn baba rẹ leyin ọpọ ifigagbaga laarin awọn ọmọ oye to le ni mẹwa, ti wọn dìjọ du ipo.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Ọjọ nla si ni ọjọ Kẹrinla osu Kinni ọdun 1971 ti atọbatẹlẹ ko to jọba, Lamidi Atanda Olayiwola Adeyemi gori itẹ awọn baba nla rẹ.