Alaafin oyo Bashorun: Mọ̀ nípa Baṣọ̀run ìlú Oyo, Oloye Yusuf Akinade Ayoola tí yóò delé de Aláàfin tuntun

Lọwọlọwọ, Oloye Yusuf Akinade Ayoola, ni Baṣọrun ilu Oyo.
Àkọlé àwòrán, Lọwọlọwọ, Oloye Yusuf Akinade Ayoola, ni Baṣọrun ilu Oyo.

Lati ọjọ ti Alaafin Lamidi Adeyemi III ti waja, ni ipo olori nilu Oyo ti ṣofo.

Ṣugbọn gẹgẹ bi itan ṣe sọ, Baṣọrun, to jẹ oloye agba, ati olori ogun, ni yoo dele titi Alaafin miran yoo fi jẹ.

Lootọ ni Alaafin jẹ ọba alade to n dari ilu Oyo lati igba atijọ, ṣugbọn awọn oloye, ti a mọ si Oyomesi, lo ma n ṣe amojuto ati akoso ilu.

Oloye agba ti a mọ si Baṣọrun si lo ma n jẹ olori fun awọn Oyomesi.

Lati igba atijọ, ẹnikẹni to ba jẹ Baṣọrun, ni aṣẹ wa lori iyansipo ẹni ti yoo ba di Alaafin.

Bakan naa ni agbara rẹ pọ debi pe, o wa ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu ti Alaafin.

Yatọ si pe o jẹ alaṣẹ to ga julọ fun awọn ọmọ ogun ilu Oyo, Baṣọrun tun ni agbara lati ṣeto ọdun ibilẹ.

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

Taa ni Baṣọrun ilu Oyo ti yoo dele de Alaafin?

Lọwọlọwọ, Oloye Yusuf Akinade Ayoola, ni Baṣọrun ilu Oyo.

Oun si ni ireti wa pe yoo di oludari ni aafin Oyo, titi wọn o fi yan Alaafin tuntun.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

O ti lo ọdun mẹrinla gẹgẹ bi Baṣrun, eyi to tumọ si pe Alaafin Adeyemi lo yan sipo.

Gẹgẹ bi Agbaakin ti ilu Oyo, Oloye Asimiyu Atanda ṣe sọ, Baṣọrun ni igbakeji Alaafin ko to o waja.

Oye naa si jẹ oye idile.

Àkọlé fídíò, Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

Bakan naa lo sọ pe Baṣọrun Ayoola ni yoo ddari ilana ti wọn o fi yan Alaafin tuntun ti akoko ba to .

Ṣugbọn ko le da yan-an lai si idasi awọn ọmọ ẹgbẹ Oyomesi yo kù.

Awọn to wa ninu igbimọ Oyomesi ni: Baṣọrun, Agbaakin, Samu, Alapinni, Lagunna, ati Akiniku.