Aláàfin's Death: Ẹ yé fi ìpapòdà àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Oyo kọmi lọ́rùn - Gómìnà Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ké gbàǹjarè sí àwọn ènìyàn láti má sọ òun lẹ́nu lórí bí àwọn lọ́balọ́ba pàápàá àwọn Ọba onípò kìíní ṣe ń papòdà ní ìpínlẹ̀ Oyo.
Makinde sọ àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó lọ bá àwọn Oyomesi kẹ́dun lórí ìpapòdà Aláàfin ìlú Oyo tó wàjà lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kẹrin, ọdún 2022.
Ní kété tí Aláàfin re ìwàlẹ̀ àṣà ní àwọn ènìyàn pàápàá lórí ẹ̀rọ ayélujára ti ń fi ẹnu kun gómìnà Seyi Makinde wí pé àwọn Ọba ńláńlá ní ìpínlẹ̀ Oyo kàn ń gbésẹ̀ ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé.
- 'Aláàfin ti rí ikú rẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tó wàjà, ó sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó tó kú'
- Òrumọ́jú ní ara Oba Lamidi Adeyemi wọ káà ilẹ̀ lọ ní Báárà gẹ́gẹ́ bí ìṣe ìran Yorùbá ṣe làá kalẹ̀
- Nínú àwòràn, wo ìgbà ayé Aláafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta tó lọ bá àwọn Baba Ńlá rẹ̀
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
- Ààrẹ Buhari, Ooni Ile Ife, Obasanjo kẹ́dùn Alaafin Oyo tó wàjà
- Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà
- Kéte ti Baba dákẹ́ ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ti bẹ̀rẹ̀ l'Áàfin - Ẹ wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Aafin Oyo
- Àṣírí ńlá tó ń bẹ láàrín Alaafin àtàwọn onílù rẹ̀ rèé
- Ta ni Yorùbá ń pè ní Abọ́bakú?
Ọba onípò kìíní mẹ́ta papòdà láàárín oṣù márùn-ún
Bí ẹ ò bá gbàgbé, Soun ti ìlú Ogbomoso, Ọba Jimoh Oyewumi ló kọ́kọ́ darapọ̀ àwọn babańlá rẹ̀ lọ́jọ́ Kejìlá, oṣù Kejìlá, ọdún 2021 kí Olubadan náà tó tẹ́rí gbaṣọ ní ọjọ́ Kejì, oṣù kìíní, ọdún 2022 tí Aláàfin sì tún wáyé báyìí.
Èyí túmọ̀ sí pé láàárín oṣù márùn-ún péré ní Ọba ńlá mẹ́ta ti lọ ní ìpínlẹ̀ Oyo.
Gómìnà wá rọ àwọn ènìyàn láti yé lọ ikú àwọn Ọba alayé náà mọ́ òun lọ́rùn àti wí pé kí gbogbo àwọn Ọba náà ló gbé ayé ire tí wọ́n sì dàgbà kí ọlọ́jọ́ tó dé sí wọn.
Bákan náà ló sọ àrídájú rẹ̀ wí pé ètò ìsìnkú tó gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀ ni ìjọba yóò ṣe fún Aláàfin gẹ́gẹ́ bí àwọn ti ń ṣe látẹ̀yìnwá.
Bẹ́ẹ̀ náà ló pàrọwà sí àwọn Oyomesi wí pé kí wọ́n má jẹ̀ ẹ́ kí yíyan ọmọ oyè tí yóò jẹ Aláàfin falẹ̀.
Makinde ṣàlàyé wí pé ohun tí Aláàfin Adeyemi tó gbésẹ̀ máa ń fi gbogbo ayé rẹ̀ sọ ni wí pé òun kò fẹ́ kí àpèrè baba òun ṣófo fún ọjọ́ pípẹ́ lẹ́yìn tí òun bá wàjà.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ó fi kun wí pé bó ṣe jẹ́ pé ọdún méjìlélàádọ́ta ni Ọba Adeyemi kẹta lò lórí àpèrè àwọn babańlá rẹ̀ kò dùn mọ́ àwọn wí pé Aláàfin fi wọ́n kalẹ̀ ní àsìkò yìí.
Ó ní ipa Aláàfin nínú àṣà àti ìṣẹ̀ṣe Yorùbá kò kéré ní èyí tí yóò ṣòro láti gbàgbé ní kíákíá.
Bákan náà ló tẹ̀síwájú wí pé láti ìgbà tí Aláàfin ti re ìwàlẹ̀ àṣà ní àwọn ènìyàn ńlá ti ń pe òun káàkiri gbogbo Nàìjíríà láti báwọn kẹ́dùn ẹni ire tó lọ.
Ó ní èyí túmọ̀ sí pé Aláàfin Adeyemi gbé ìgbé ayé tó ṣe yangàn nígbà tó wà lókè eèpẹ̀.


















