Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

Àkọlé fídíò, Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

Ko seni ti ko ni papaoda laye...

Asiko koowa lo ṣọtọọtọ.

Alaafin, Oba Lamidi Adeyemi re iwale asa lọ darapọ mọ awọn BabaNla rẹ ni ọjọ kẹtalologun, osu kẹrin, ọdun 2022.Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré

Awọn to máa n dá Baba laraya nigba aye rẹ̀, awọn to n ki oriki fun Oba Atanda abẹsẹkubiojo to gunwa lori itẹ̀ àwọn Baba rẹ fun odindin ọdun mejilelaadọta tun ki oriki Oba Adeyemi bi o se dagbere fun aye pe o digbose.

Awọn to n kọrin fun Baba ni afin Oyo yii tun kọrin aro lorisiirisii lati fi yẹ Oba Lamidi Adeyemi keta si lẹyin ti baba papoda tan.