Money Ritual in Ondo: Abilékọ tí àlè fẹ́ fi ṣe ètùtù ọlà wà lẹ́sẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run

Funmilola Ogundare

Oríṣun àwòrán, Ngozi Igbo/Facebook

Asamọ ọrọ kan lo ni iyawo ile to ba n yan ale, bi ko ba pa ara rẹ, yoo se iku pa ọkọ rẹ.

Bi ọrọ se ri gan ree pẹlu abilekọ kan, Funmilola Ogundare to ni ọrẹkunrin kan ti wọn dijọ n yan ara wọn ni ale.

Ifẹ ikọkọ naa gbadun mọ awọn mejeeji ti abilekọ naa se pinnu lati lọ sun sile ọrẹkunrin rẹ naa.

Se ọjọ ti a ba sọnu, gaga ni ara n ya ni, ti Funmilola Ogundare ko si mọ pe oorun iku ni oun fẹ lọ sun nile ọkunrin naa.

Bawo ni isẹlẹ naa se waye?

Ọrẹkunrin Fumilola, ti ẹnikẹni ko tii mọ orukọ rẹ, amọ ti wọn pe ni agbabọọlu, lo sadede wa gba ilegbe kan sinu agbo ilegbe GRA, ni Ijapo, nilu Akure.

Ọjọ kẹta to si ko de ilegbe naa lo ransẹ pe abilekọ naa pe ko wa sun mọjumọ ti oun, ki awọn le jọ fi ara kinra.

Àkọlé fídíò, Oru tí olóríibú máa ń di olóríire ni "Laylatul Qadr", tóo bá bẹ Ọlọ́hun, orú agbára gidi ni - Akeugbagold

Funmilola lọ sile naa lootọ, ti wọn si dijọ sun papọ amọ lọganjọ oru ni ale naa fa ada yọ, to si n kun wẹlẹwẹlẹ bii ẹran ọya.

Se ni obinrin naa bẹrẹ si lọgun pe ki awọn aladugbo wa gba oun, ti ero si tete pe siwaju ile naa.

Amọ ki wọn to le raye wọle doola ẹmi Funmilola lọwọ afurasi apaayan naa, onitọun ti na papa bora.

Obirin naa si ti fi ara gba ọgbẹ kọja sisọ pẹlu, ti gbogbo ara rẹ si kun fun ọgbẹ ati ẹjẹ.

Se ni awọn ara adugbo sare ke si ikọ Amotekun pe ko wa wo ohun to n sẹlẹ nibẹ., ti wọn si gbe obinrin naa lọ sile iwosan fun itọju.

Sugbọn ile iwosan akọkọ ti wọn gbe abilekọ naa lọ lo kọ lati gba obinrin naa wọle tori ọgbẹ ara rẹ kọja afojuri.

Wọn si gba awọn to gbe wa nimọran pe ki wọn maa gbe lọ sile ẹkọasẹ isegun University of Medical Sciences, Teaching Hospital, to wa ni Akure.

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

Aya Gomina Akeredolu tẹwọgba itọju abilekọ naa, o sanwo itọju rẹ:

Akọwe apapọ fun ajọ to n gbogun ti iwa ipa laarin takọtabo ati ibalopọ, (OSAA-GBV), Amofin Bola aya Joel-Ogundadegbe salaye pe oun gbọ si isẹlẹ naa.

O ni ileesẹ ọlọpaa ati ajọ OSAA-GBV labẹ akoso aya gomina Ondo, Betty Akeredolu si ti gbe igbesẹ lori isẹlẹ naa.

Ogundadegbe ni aya gomina ti pasẹ pe ki wọn gbe Funmilola lọ sile iwosan fun itọju.

Bakan naa lo fikun pe Betty aya Akeredolu ti san gbogbo owo to yẹ fun itọju obinrin naa, ko le tete ri itọju to peye gba.

"Abilekọ naa ti n fi ẹrọ mi afẹfẹ simu nile iwosan, to si ti ji saye pada amọ ko tii le da ohunkohun mọ, ti ko si tun ni okun lati rin pẹlu.

Ogundadegbe tun tọkasi pe ko tii si ẹnikẹni to mọ iru ẹda ti ale obinrin naa jẹ yatọ si pe awọn aladugbo ni agbabọọlu ni.

O wa yan pe Funmilola naa nilo ki wọn gbe lọ sile iwosan Federal Medical Centre ki awọn dokita onisegun ọpọlọ le se ayẹwo ori rẹ ti ọgbẹ nla kan wa.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú