2023 Election: Wike ní àwọn agbésùnmọ̀mí ru igi oyin tí òun bá dí ààrẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rivers State Government
Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti ni awọn agbebọn ati agbesunmọmi ti ru igi oyin ni kete ti oun ba ti di aarẹ lorilẹede Naijiria.
Wike sọ eyi lasiko to n jiroro pẹlu awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP lati ipinlẹ Taraba lori igbiyanju rẹ lati dije dupo aarẹ ni ọdun 2023.
O ni iṣoro ti ẹgbẹ oṣelu PDP gbọdọ koju ni lati ri pe eto aabo Naijiria ni ojutu ki eto aabo le lojutu.
- Ọ̀nà àti yọ ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́ àti obìnrin kúrò láwo òṣèlú ni owó fọ́ọ̀mù #100m tí APC kéde - CISLAC
- Fayose kìí bá wọn jẹ ìjẹkújẹ, bí Aisha Buhari bá fẹ́ fún èèyàn l'Oúnjẹ ko wá aláìní lọ
- Wo àwọn ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa gbajúgbajà olóri ẹ̀mí, Tope Alabi
- Erin wóó! Ààrẹ Kenya tẹ́lẹ̀, Kibaki jáde láyé lẹ́ni ọdun 90
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Ogun tẹ ọkùnrin ọgbọ̀n ọdún tó fi ipá ba obìnrin lò nínú ṣọ́ọ̀ṣì
''Ohun to damiloju ni pe ti awọn agbebọn ba gbọ orukọ mi wọn ma sare kabakaba fun ẹmi wọn nitori mi o ni gba fun wọn.''
''Ma a ri pe mo ṣiṣẹ bi adari ikọ ọlọgun lorilẹede Naijiria''

Oríṣun àwòrán, Google
Wike fikun un pe oun yoo sa gbogbo ipa oun lati ri pe inu awọn ọmọ Naijiria dun.
Bakan naa ni lati oun yoo ri pe itẹsiwaju wa ni ẹka eto agbẹ, eto aabo, ati eto ọrọ aje ni Naijiria.
"100m tí APC ń bèrè fún owó fọ́ọ̀mù kò ní jẹ́ kí àwọn tó nífẹ́ aráàlù dé ipò ìjọba"
Onimọ nipa ọrọ oṣelu kan, to tun ti fi igba kan du ipo gomina ni ipinlẹ Ondo, Dotun Ojon ti sọ pe awọn to ni ọpọlọ ko ni lanfaani lati dije du ipo Aarẹ ni Naijiria mọ ni bayii ti awọn ẹgbẹ oṣelu n kede ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu naira gẹgẹ bii owo fọọmu.

Oríṣun àwòrán, @tweetfm74
Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC kede ọgọrun miliọnu naira gẹgẹ bii owo fọọmu fun ẹnikẹni to ba nifẹ lati du ipo Aarẹ, ati aadọta miliọnu naira fun ẹni to ba nifẹ lati du ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣẹlu naa.
Ojon sọ fun BBC Yoruba pe lootọ, awọn ẹgbẹ oṣelu nilo ọpọlọpọ owo lati gbe ẹru ẹgbẹ naa, amọ iye owo ti ẹgbẹ APC kede yii kọja ojuẹ.
- Wo bí o ṣe lè so fóònù rẹ pọ̀ mọ́ àwọn ǹkan tí ọmọ rẹ ń wò lórí fóònù rẹ̀
- Mo tọrọ àforíjì lórí fídíò tí mo gbé jáde, tó ń mú àwọn èèyàn pè mí - Bukunmi Oluwashina
- Ṣé lóòtọ́ ni pé mo leè jẹ́ ''virgin" kí ẹ̀jẹ̀ má sì yọ lálẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó? - Ìwádìí fìhàn
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá sọ ìgbà tí wọ́n ó gbé ọkọ akọrin Osinachi tó dolóògbé lọ sí iléẹjọ́
- Ọ̀nà àti yọ ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́ àti obìnrin kúrò láwo òṣèlú ni owó fọ́ọ̀mù #100m tí APC kéde - CISLAC
- Ṣé lóòtọ́ ni àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA ń lọ́ àwọn awakọ̀ lọ́wọ́ gbà l'Eko? Àwọn èèyàn jáde fi ẹ̀hónú hàn
- Ọ̀rọ̀ Ayo Adebanjo pé kí Tinubu, Osinbajo yọwọ́ ní dídu ipò ààrẹ, ṣé gbogbo ẹgbẹ́ Afenifere lọ́wọ́ síi báyìí?
- 'Ó dá mi lójú pé kò ní sí ìdìbò sípò gómìnà ní Osun, Ekiti láíláí ní ọdun 2022!'
- Oluwo, tètè yípadà nídìí títàbùkù Yorùbá tori ewe ń bẹ̀, òògùn wà
Gẹgẹ bii ohun to sọ "Eyii tumọ si pe awọn to ni ọpọlọ, atawọn to ni ọkan lati ṣiṣẹ fun awọn eeyan, o ṣeeṣe ki wọn ma le ri irufẹ awọn owo ti awọn ẹgbẹ oṣelu wọnyii n bere fun ko silẹ."
"Eyii yoo mu ko ṣoro fun awọn to ba le ṣiṣẹ daadaa amọ ti wọn ko ni owo lati ri anfaani lati de ipo ijọba."
"Ti ẹ ba woo daadaa, ẹni to jẹ ogoji ọdun, to ni ifẹ araalu lọkan to si ja fafa, amọ nibo lo ti fẹ ri iru owo to fẹ fi gba fọọmu ti a n sọ yii?"
Ṣe lootọ ni APC fẹ yọ ọwọ awọn kan kuro lawo eto idibo ọdun 2023?
Ninu erongba Ojon, iye owo fọọmu ti APC kede kii ṣe ọna lati yọ ọwọ awọn oludije kan kuro lawo eto idibo ọdun 2023.
O ṣalaye pe gbogbo awọn to ti fi erongba wọn lede lo koju oṣuwọn lati gba fọọmu naa, amọ ẹgbẹ oṣelu APC kan n wa owo ni.
Ojon ni "APC kan n wa owo ni, ati pe wọn tun fi owo fọọmu naa sọ pe awọn lo wa ni ijọba ati pe wọn ko si ni kilaasi awọn ẹgbẹ oṣelu yoku."
Dotun Ojon sọ siwaju pe kii ṣe APC nikan lo n ṣe irufẹ nnkan bayii, gbogbo ẹgbẹ oṣelu to ba ti wa ni ijọba lo maa n kede owo fọọmu gọbọi, amọ ko daa to.
Ohun ti awọn araalu le ṣe
Ojon woye pe kaka ki awọn araalu tabi ki oloṣelu maa fapa janu lori iye owo ti APC kede, wọn le dẹyin lẹyin APC ki wọn si ba ẹgbẹ mii lọ.
O ni "Kii ṣe ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP nikan lo wa ni Naijiria, awọn eeyan lọ si ẹgbẹ mii."
"Ti awọn araalu yin ba wa lẹyin yin, ẹ ko nilo lati wa ninu ẹgbẹ oṣelu ti wọn yoo ti maa bere N100m lọwọ yin, ẹ le lọ sinu ẹgbẹ mii."
"Nitori ọgọrun miliọnu naira owo fọọmu ti APC n bere fun yii to fun awọn ẹlomiran lati da ẹgbẹ oṣẹlu silẹ, ki wọn si ṣe awọn ilana to yẹ ninu naa ko le ni gbongbo."















