Kenyan Ex-President Kibaki dies: Wo àwọn tó ń kẹ́dùn ààrẹ Kibaki tó jáde láyé

Awọn adari agbaye ti n ṣe idaro ati ibanikẹdun aarẹ orileẹde Kenya tẹlẹ Mwai Kibaki to jade laye lonii ọjọ Ẹti.
Ikede naa jade ni owurọ ọjọ Ẹti ọjọ Kejilelogun oṣu Kẹrin ọdun 2022.
Aarẹ Kenya to wa lori oye bayii, Uhuru Kenyatta ti ni inu ọfọ ati idaro ni orilẹede naa yoo wa titi ti oorun yoo fi wọ̀ lọjọ ti wọn yoo gbe Mwai Kibaki bọ ilẹ.
Igbakeji aarẹ to wa lori oye bayii, William Ruto to tun jẹ ọkan lara awọn Minisita labẹ iṣejọba Ọgbẹni Kibaki nigba naa sọ pe ọmọ onil daadaa ni.
Bakan naa, oloṣelu ẹgbẹ alatako, Musalia Mudavadi to j igbakeji olootu ni ijọba Kibaki ti fi ibanikẹdun rẹ sita pe: "Ọmọ orilede Kenya to kopa ninu ijiya lati gba orilẹede naa la ni oko ẹru to si wa fi ipilẹ ọrọ aje to n so eso rere eyi ti Kenya n ri bayii ni".
Ẹwẹ, aar Kenyatta ti ni eto isinku to ni iyi ni wọn yoo ṣe fun aarẹ ana yii.
Nibayii, gbogbo asia orilẹede naa ni wọn ti paṣẹ pe ki wọn gbe wọn walẹ si agbede meji ofurufu ko maa fo.
Kibaki jẹ aarẹ laarin ọdun 2002 si ọdun 2012.















