Akeugbagold on Laylat al-Qadri: Ohun tí yóò ṣẹ́lẹ̀ rèé tí gboogbo Mọ̀láìkà yóò sọ̀kalẹ̀ wá sí ayé ni òru agbára yìí
Gẹgẹ bi wọn ṣe maa n reti oṣu ti yoo sọ ọjọ ti awẹ yoo bẹrẹ, oru pataki kan tun wa ti awọn Musulumi maa n foju sọna fun ti wọn si maa n waa lati mọ ọjọ ti yoo bọ si pato. Ki ni idi ti wọn fi n wa a?
Ọjọ mẹwaa to kẹyin oṣu Ramadan ni oru ti wọn n pe ni Lailatu-l-Qodri.

Alaga Ajọ awọn Musulumi ni ipinlẹ Oyo, Sheikh Al-Wasir Taofeek Akeugberu ti ọpọ mọ si Akeugbagold ṣalaye pe oru iyi, oru agbara ti Ọlọrun maa n ṣe ọla.
Onimọ nipa ẹsin Islam naa ni "oru ti oloriire le di oloriibu ti ko ba ṣọra ni, kọda, oru ti oloriibu o di oloriire ni."
O ni ọjọ ti yoo ṣẹlẹ, ko sẹni ti yoo mọ amọ ṣiṣọ asiko ṣe pataki gidi gan ninu asiko aawẹ.
Lara awọn nkan ti yoo jẹ ki laada rẹ pe ni: didide yan nọfila loru, too ba le ṣe e tori o ni o pataki gan loju Ọlọrun.
Bakan naa lo mẹnu ba yiyan nọfila to si ni ki onikaluku mura si ẹsin ati ibaada lasiko Ramadan.

Anọbi o tun ara ṣe ni nkan bii ọjọ 19 aawẹ
"Ṣiṣọ akoko ṣe pataki ninu aawẹ, ọpọ eeyan ni ko mọ pe asiko ẹ pataki ninu aawẹ".
Ni ọjọ kọkandinlogun aawẹ, Anọbi yoo tunra ṣe, Anọ́bi yoo tun sokoto rẹ san, yoo tun ara ṣe yoo wa sọ pe na'am".
Akeugbagold gba awọn Musulumi nimọran gbe ki wọn foju sọna gidi gan de oru agbara naa lọhun ti gbogbo awọn Mọlaika yoo sọkalẹ wa sorilẹ aye.