Hajj: Àjọ alálàájì ní owó Hajj ọdún yìí yóò tó N2.5m fún arìnrìnàjò kọ̀ọ̀kan

Ajọ Alalaji to n se kokari irinajo lọ silẹ mimọ Hajj, (NAHCON) ti kede pe arinrinajo silẹ mimọ kọọkan le san to miliọnu meji ati aabọ naira.
Owo ti wọn yoo fi lọ si Mecca lọdun yii si lo fi idaji le si iye ti arinrinajo kọọkan san lọdun 2019 ti wọn seto Hajj kẹyin, ki arun Coronavirus to wọle de.
Eyi fihan pe o le ni miliọnu kan naira to owo Hajj tọdun 2022 ta wa yii fi le si iye ti arinrinajo kọọkan san lọdun 2019.
- Wo bí o ṣe lè so fóònù rẹ pọ̀ mọ́ àwọn ǹkan tí ọmọ rẹ ń wò lórí fóònù rẹ̀
- Mo tọrọ àforíjì lórí fídíò tí mo gbé jáde, tó ń mú àwọn èèyàn pè mí - Bukunmi Oluwashina
- Ṣé lóòtọ́ ni pé mo leè jẹ́ ''virgin" kí ẹ̀jẹ̀ má sì yọ lálẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó? - Ìwádìí fìhàn
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá sọ ìgbà tí wọ́n ó gbé ọkọ akọrin Osinachi tó dolóògbé lọ sí iléẹjọ́
- Ọ̀nà àti yọ ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́ àti obìnrin kúrò láwo òṣèlú ni owó fọ́ọ̀mù #100m tí APC kéde - CISLAC
- Ṣé lóòtọ́ ni àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA ń lọ́ àwọn awakọ̀ lọ́wọ́ gbà l'Eko? Àwọn èèyàn jáde fi ẹ̀hónú hàn
- Ọ̀rọ̀ Ayo Adebanjo pé kí Tinubu, Osinbajo yọwọ́ ní dídu ipò ààrẹ, ṣé gbogbo ẹgbẹ́ Afenifere lọ́wọ́ síi báyìí?
- 'Ó dá mi lójú pé kò ní sí ìdìbò sípò gómìnà ní Osun, Ekiti láíláí ní ọdun 2022!'
- Oluwo, tètè yípadà nídìí títàbùkù Yorùbá tori ewe ń bẹ̀, òògùn wà
Alaga ajọ alalaaji NAHCON labẹ ijọba apapọ, Alhaji Zikrullahi Hassan lo sisọ loju ọrọ yii ni Ọjọbọ nibi ipade igbimọ alasẹ ajọ naa.
Ipade ọhun lo wa fun ipalẹmọ feto Hajj fọdun ta wa yii.
Nigba to n salaye idi ti alekun fi ba owo Hajj naa, Hassan ni pasipaarọ owo naira ilẹ wa si tilẹ okeere to mẹhẹ lo sokunfa alekun owo Hajj naa.
Bakan naa lo ni awọn owo ọja to gbẹnu soke pẹlu ida mẹẹdogun ninu ọgọrun owo ori ọja ti wọn n san eyi tawọn alasẹ ilẹ Saudi Arabia n beere fun naa sda kun alekun owo Hajj naa.
"Tẹlẹtẹlẹ lọdun 2019, naira mẹfalelọọdunrun ni a n sẹ owo naira si dọla amọ o ti di naira mẹwalenirinwo naira si dọla kan bayii.
Gẹgẹ bi gbogbo wa se mọ pe ida mẹtadinlọgọrun pasipaarọ owo ilẹ wa si tilẹ okeere ni isẹ Hajj n ko eyi ta n na lori ounjẹ, owo baalu atawọn nnkan miran.
"Ni afikun eleyi, awọn alasẹ ilẹ Saudi Arabia tun ti se afikun owo ori ọja tiwọn lati ida marun si mẹẹdogun.
A tiraka ni iha tiwa lati mu adinkun ba awn isoro to le fẹ koju awọn arinrinajo nitori awọn ipenija naa."
Bawo ni wọn yoo se pin aaye Hajj fun ipinlẹ kọọkan?
Hassan salaye pe ninu aaye arinrinajo bii ẹgbẹrun lọna mtalelogoji ati mẹjọ (43,008) tijọba Saudi fun Naijiria lọdun yii, aaye arinrinajo ẹgbẹrun lọna mẹrinlelọgbọn o din mẹrinlelogun (33,976 ) ni wọn yoo fun awọn ipinlẹ lapapọ.
O ni ipinlẹ Kaduna ati Sokoto ni yoo gba ipin aaye Hajj to pọ ju, Kaduna yoo gba aaye ẹgbẹrun meji aabo din diẹ (2491), ti Sokoto yoo si gba ẹgbẹrun meji abọ o din diẹ naa (2404)
Bakan naa lo salaye pe awọn ipinlẹ bii Bayelsa, Imo ati Rivers ko ni ipin aaye Hajj kankan lọdun 2022 yii nitori wọn ko ba ilana to yẹ nidii to de sise Hajj mu.
















