Guru Maharaji: Oluwo, kò sọ òótọ́ rí, jìbìtì ló fi ń lògbà

Oluwo ati Guru Maharaji

Oríṣun àwòrán, Oluwo of iwo

Asaaju ẹsin One Love Family, Sat Guru Maharaji ti ransẹ ikilọ si Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni.

Guru Maharaji, lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nibudo rẹ to wa nilu Ibadan, fi oju abuku wo awọn igbesẹ ti Oluwo n gbe eyi to ni o fi n tapa si ilẹ Yoruba.

Lara awọn igbesẹ bẹẹ, gẹgẹ bi Guru Maharaji ti wi ni fifi ara rẹ pe Emir, sisọ awọn ede alufansa si iran Yoruba, bo se fẹ iyawo lapa oke ọya ati titabuku asa Yorua lapapọ.

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

Asaaju ijọ One Love Family naa ni ko sẹni to le tapa si ilẹ Yoruba to le mu jẹ, nitori ọjọ ẹsan n bọ.

A fẹ ki Oluwo ranti pe baba kan lo bi awọn, ẹni ti ko de ipo tawọn de loni yii.

Nitori naa, a fẹ ki wọn ye fi orisirisi abuku lọ wa, mo gbọ nigba kan ti wọn ni awọn fẹ joye Emir nitori ifẹ ti n bẹ laarin awọn ati Arewa.

Irọ ni, jibiti ni wọn fi n rin, wọn ko sọ otitọ ri, baba wa naa ni wọn amọ wọn fẹ fi eru gba ibukun ni wọn tun se gba ibi ẹsin wọle.

Àkọlé fídíò, 'Fásitì Nàìjíríà kò gbà mi wọlé ló mú mi sá lọ Ukraine, àmọ́ ohun tí ojú mi rí nínú ogun náà rèé kí ń tó sá wá Nàìjíríà'

Ẹ ba wa bẹ Oluwo pe ko ma fi aye silẹ bayii lati ipasẹ iwakiwa to n hu, a si nilo wọn lasiko yi

O wa yẹ ki Oluwo maa ranti pe ewe n bẹ o, ẹ sọ fun wọn ki wọn tete yipada nitori asa ati ise Yoruba lo wa nipo kinni jake jado agbaye.

Ẹni to ba ni ko rii bẹẹ, ko wa sọ jade, ko wa koju mi."

Bakan naa ni Guru Maharaji fikun pe ohun to n ba ni ninujẹ, ti ko si bojumu ni awọn iwa Oluwo naa.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe rí ọ̀pọ̀ Mílíọ̀nù Nàírà tí mo sì dáà padà fún Ọlọ́pàá lọ́dún 1971 àmọ́ ǹkan t'íjọba sọ rèé - Baba Shonubi

O wa fikun pe ẹnikan kii tapa si ẹya Yoruba, ẹni to ba tapa si Yoruba, Iya yoo jẹ.

Nigba to n sọrọ lori bi Oluwo se lọ mu iyawo wa nilẹ Hausa, Guru Maraji ni ti eeyan ba pẹ lori imi, esinkesin yoo bo.

O ni Naijiria ti goke agba, ọlaju si ti de amọ ohun to se pataki fun Oluwo ni pe ko ma gbagbe asa.

"O seese ki Oluwo mọ ohun to ri lara obinrin yẹ, emi o gbọ iru rẹ ri, kii si se Kabiyesi wa lo yẹ ko se bẹẹ́."

Àkọlé fídíò, Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn