Chrisland school scandal video: Pín fọ́rán ìbálòpọ̀ ọmọdé kí o fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá jura - Agbẹjọ́rò

Aworan ibalop ati abo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbẹjọro kan, Olaiya Kareem ti sọ pe o lodi si ofin Naijiria ki eeyan maa pin fọran to ṣafihan ibalopọ ọmọde kaakiri.

Kareem sọ fun BBC Yoruba ninu ifọwerọ kan pe irufẹ ẹni to ba pin fọran bẹẹ le fi ẹwọn ọdun mẹwaa jura tabi ko san owo itanran ogun miliiọnu naira, tabi ko fara gbe mejeji.

O ni "Ofin Naijiria lodi sii... ofin naa ni wọn gbe kalẹ lọdun 2015."

"Ẹsẹ kẹtalelogun, apa kinni ati ewe A ninu ofin naa sọ pe ẹnikẹni to ba pese fọran ibi ti ọmọ ti tẹ ara rẹ kalẹ fun iwa aṣẹmaṣe ṣe si ofin yii."

"Ẹnikẹni to ba ṣagbatẹru bi irufẹ fọran bẹẹ ṣe le fọnka ni ijiya to tọ si labẹ ofin Naijiria."

"Yatọ si pinpin irufẹ fọran bayii lori ayelujara, ijiya tun wa fun ẹnikẹni to ba fi ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ pin fọran kan naa fun ẹlomiran."

Àkọlé fídíò, 'Fásitì Nàìjíríà kò gbà mi wọlé ló mú mi sá lọ Ukraine, àmọ́ ohun tí ojú mi rí nínú ogun náà rèé kí ń tó sá wá Nàìjíríà'

"Ijiya naa ni pe irufẹ ẹni bẹẹ yoo fi ẹwọn ọdun mẹwaa gbara tabi ko san ogun miliọnu naira ọwo itanra tabi ko jiya nnkan mejeji."

Agbẹjọro Kareem ṣalaye siwaju si pe ijiya tun wa fun ẹnikẹni ti wọn ba ṣe si ofin yii labẹ orulẹ rẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti amofin naa sọ, iyatọ wa laarin ọmọde ati ọdọ nipa ti ọjọ ori.

O ni gẹgẹ bii agbekalẹ ajọ iṣọkan agbaye, UN, ati ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọde lagbaye, UNICEF, gbogbo ẹni to ba wa laarin ọdun kan si ọdun mejidinlogun ni ọmọde.

O fi kun pe gbogbo ẹni ti ọmọde ba wa labẹ rẹ ti jẹ gbese itọsọna irufẹ ọmọde bẹẹ, nitori naa, obi tabi alagbatọ ti wọn ba ya fọran ibalopọ ọmọde tabi pin fọran ibalopọ ọmọde labẹ rẹ ti rugi oyin labẹ ofin.

Àkọlé fídíò, Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn

Ki ni ijiya ẹṣe yii ni ipinlẹ Eko?

Agbẹjọro Kareem ni ijiya ẹsun naa ni ipinlẹ Eko pọ ju ijiya to wa ninu ofin ijọba apapọ Naijiria lọ.

O ni "Ijọba ipinlẹ Eko ni, ti ẹ ba ri iru fọran bayii, ti ẹ si n pin kaakiri, ẹṣe ni, iru ẹni ti wọn ba mu yoo fi ẹwọn ọdun mẹrinla gbara."

Amofin naa pari ọrọ rẹ pẹlu imọran fun awọn obi at alagbatọ lati maa bojuto awọn ọmọ wọn.

Lẹyin naa lo sọ pe ijiya kan lo wa fun gbogbo ẹni to ba ya fọran naa, to ba n pin ati ẹni ti wọn ya tabi pin ni sakani rẹ.

Ki ni awọn onimọ nipa iwuwasi ọmọde sọ?

Ẹwẹ, onimọ kan nipa bi awọn ọmọde ṣe maa n wu iwa, Dairo Oluremi ti gba awọn obi lamọran lati maa ṣọra fun awọn ohun ti wọn ba n ṣe niwaju awọn ọmọ wọn.

O ni o yẹ ki awọn obi maa yẹba fun awọn ọmọ wọn ti wọn ba fẹ ṣe bii lọkọ-laya nitori ọlọpọlọ pipe ni awọn ọmọ aye ode oni, o si ṣoro fun wọn lati gbage ọpọ nnkna ti oju wọn ba to ninu ile.

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà