Taraba bomb blast Àdó olóró búgbaàmù nílú Iware, èèyàn márùn-ún ti kú

Aworan ileeṣẹ Ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, AFP

O kere tan, eeyan marun lo ti dagbere faye bayii nibi ibugbamu kan ti eeyan bii mkandinlogun si farapa yanayana nibẹ.

Ni ipinlẹ Taraba ni ibugbamu naa ti waye nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun ni agbegbe Iware ni ilu Jalingo tii ṣe olu ilu ipinlẹ naa.

Akọroyin BBC to jabọ iroyin yii, Chris Ewokor ni Agbẹnusọ ọlọpaa, Abdullahi Usman sọ pe wọn ti pa ọkan lara awọn to ṣe iṣẹ laabi ọhun amọ ko tii ye bi iku rẹ ṣe waye.

Àkọlé fídíò, 'Fásitì Nàìjíríà kò gbà mi wọlé ló mú mi sá lọ Ukraine, àmọ́ ohun tí ojú mi rí nínú ogun náà rèé kí ń tó sá wá Nàìjíríà'

Eeyan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ koro ni nkan abugbamu naa wa ninu baagi kan ti wọn si gbe e pamọ si ibudo kan ti wọn ti maa n mu ọri.

Ẹwẹ, awọn ọlọpaa ti n ṣe iwadii lọwọ lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ yii gangan.

Nibo ni ilu Iware wa?

Ilu Iware jẹ ilu ti o fẹẹ jẹ pe kiki da ọja ni wọn maa n na nibẹ ti awọn ọlọja maa n korajọ si lati ibi gbogbo ni orilẹede Naijiria fun katakara ẹran ọsin ati ounjẹ jijẹ.

Ni ọdun mẹwa sẹyin, awọn eeyan mẹta to gbe ado oloro lori ọkada ṣ ikọlu si ọkọ iṣẹ ọga agba ọlọpaa kan ni ilu naa.

Eeyan mọkanla tawọn ti awọn to ṣe ikọlu naa lo ku ninu ibugbamu naa eyi ti wọn di ẹbi rẹ ru ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Boko Haram.

Bẹ ni kii ṣe igba akọkọ niyi ti ikọlu ati igbesunmmi ti n ṣẹlẹ ni iha Ariwa orilẹede Naijiria.