Bomb blast in Afikpo: Ṣé lóòtọ́ ni àdó olóró bú ní iléèwé kan ní ìpínlẹ̀ Ebonyi lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun?

Oríṣun àwòrán, AP
Ọsan ọjọ Iṣẹgun ni iroyin gba gbogbo ori ayelujara pe ado oloro bu ni ileewe kan ni Amaizu-Afikpo, nipinlẹ Ebonyi.
Iroyin naa sọ pe ọkunrin kan to so ado oloro mọra n gbiyanju lati wọ ileewe alakọbẹrẹ kan lati tu adoro oloro naa sibẹ.
Iroyin naa tun sọ pe ọrọ bẹyin yọ fun ọkunrin naa, nitori pe niṣe ni ado oloro to so mọ ara bu ko to o raye wọ inu ileewe naa.Eyi to fa iku rẹ lẹsẹ-kẹsẹ.
Ṣugbọn nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ebonyi sọ pe ko si nkan to jọ ibugbamu ado-oloro.
Agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye pe agolo afẹfẹ gaasi to wa lara ọlọpaa kan lo dee=de bu gbamu mọ ọ lara, to si pa ọlọpaa naa.
O ni insipẹkitọ ọlọpaa ni ọkunrin naa, to si jẹ pe afẹfẹ tia gaasi to fi n ṣiṣẹ lo bu gbamu lojiji to si pa a.
Wọn ni alaafia ti pada si agbegbe naa bayii.
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ebonyi sọ ninu atẹjade kan pe ayederu iroyin ni pe ado oloro bu.
Oluranlọwọ pataki fun gomina ipinlẹ naa lori eto iroyin ati ipolongo, Francis Nwaze sọ pe ọna meji ni iru ijamba naa ti waye.
"Yatọ si ti ọlọpaa ti agolo tia gaasi rẹ bu mọ lara niwaju ileewe, iru nkan bẹẹ tun ṣẹlẹ niwaju ile ijọba atijọ lasiko ti awọn ọlọpaa n ṣe ayẹwo awọn irin'ṣẹ wọn.
"Iṣẹlẹ akọkọ gba ẹmi ọlọpaa naa, ṣugbọn ikeji mu ifarapa fun ọlọpaa naa, to si ti wa ni ileewosan .













