Insurgency: Àdó olóró ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí sekú pa èèyàn mẹ́wàá ní Maiduguri

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN AIR FORCE HQ
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ilu Maiduguri nipinlẹ Borno sọ pe ọpọ eeyan ni ẹgbẹ agbesunmọni kan ti ran lọ si ọrun alakeji lẹyin ti wọn yin ado oloro si olu-ilu ipinlẹ naa lọjọ Iṣẹgun.
O ṣoju mi koro kan sọ pe awọn ọmọkunrin mẹsan ni ado oloro ṣeku pa nibi ti wọn ti n gba bọọlu lagbegbe Gwange niluu Maiduguri.
Akọroyin kan, Ali Chiroma to n gbe ni Maiduguri naa fidi rẹ mulẹ pe eeyan mẹrin ni ado oloro pa lagbegbe oun ni Adam Kolo.
- 'Torí Damilare, mo kara bọ agbo àwọn oní fíìmù, k'óun náà lè gòkè bíi Funmi Martins'
- Bí àsìkò ikú òṣèré Funmi, ìyá Mide Funmi Martins ṣe roo lágbo òṣèré nígbà náà nìyìí
- Ìjọba Naijiria buwọ́lu abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 fún lílò
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ń yí àwọn èèyàn sí oníbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo - Alfa Abbas
- Kò tíì sí ọ̀rọ̀ ìyàwó báyìí o, kí n tó lè sọ̀rọ̀ pé mo fẹ́ gbé ìyàwó, màá ...- Oba Oloyede Akinghare II
Iroyin kan tun sọ pe eeyan mẹwaa ni ado oloro ṣeku pa nibi iṣẹlẹ naa niluu Maiduguri.
''Nibi ti ado oloro sọlẹ si ko jina si ile wa, gbogbo awọn to farapa ni wọn ti ko lọ sile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Maiduguri, UMTH,'' Ciroma lo ṣalaye bẹẹ.
O fikun ọrọ rẹ pe agbegbe Gwange ati Adam Kolo ti ko jina si aafin Shehu ilu Borno ni iṣẹlẹ naa ti rinlẹ julọ.
Awọn olugbe ilu Maiduguri kan sọ pe awọn agbesunmọmi naa gbiyanju lati ya wọ inu ilu naa lẹyin ti wọn yin ado oloro akọkọ.
Ṣugbọn ko ṣeeṣe fun wọn lẹyin ti wọn kọju ija si wọn.
Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum ṣe abẹwo sawọn to n gba itọju nile iwosan UMTH ni Maiduguri.
Ko si ẹgbẹ agbesumọmi to tii sọ pe awọn lo wa nidi iṣẹlẹ ọhun, amọ ilu Maiduguri ni Boko haram ti bẹrẹ.
Ibẹ si ni iroyin sọ pe wọn ti n fi ẹmi eeyan bii ẹgbẹrun mẹrindinlogoji ṣofo lati ọdun 2009 ti eeyan bi miliọnu meji si ti di alai nile lori lapa ila oorun ariwa Naijiria.















