2023 Presidency: Irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni gbogbo ẹ̀sùn rẹ - Ohanaeze Ndigbo fún Oluwo lésì

Oluwo ati aworan idanimọ Ohanaeze

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Igbo ilẹ̀ Nàìjíríà Ohanaeze Ndigbo tí júwe ọ̀rọ̀ tí Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi sọ wí pé àwọn ẹ̀yà Igbo kò ṣee gbé ọkàn le pẹ̀lú ipò Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí.

Ohanaeze ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ẹ̀sùn tí Oluwo fi kan àwọn àti wí pé ìfẹ́ inú Oluwo lásán ló fi sọ̀rọ̀ láì ṣe ìwádìí láti fìdí ẹ̀rí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀.

Ọba Akanbi nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ Agbẹnusọ rẹ̀, Alli Ibraheem ti ṣáájú sọ wí pé kò sí ọmọ Nàìjíríà kankan tí yóò ní ìfọkàntán lábẹ́ ìdarí ẹ̀yà tí kìí fẹ́ fún àwọn ẹ̀yà mìíràn ní ẹ̀tọ́ wọn.

Bákan náà ló fi ẹ̀sùn kàn àwọn ẹ̀yà Igbo wí pé wọ́n máa ń dènà kí àwọn ènìyàn ẹ̀yà yòókù kó dúkìá jọ ní agbègbè wọn, léyìí tó ní kò bá òde òní mu.

Nígbà tó ń fèsì sí àwọn ẹ̀sùn Oluwo yìí, Ààrẹ àpapọ̀ fún Ohanaeze Ndigbo, Ọ̀jọ̀gbọ́n George Obiozor júwe gbogbo ẹ̀sùn náà bíi ásà tí kò ní ǹkan nínú.

Obiozor ní ó yẹ kí Oluwo lọ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ọba tí wọ́n jáde, tí wọ́n mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìgboro nítorí à ti lè máa lo inú mímọ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà yòókù pàápàá àwọn tó bá ń gbé ní agbègbè wọn.

Àkọlé fídíò, Oluwo ilu Iwo ba BBC Yoruba sọrọ lori awuyewuye pẹlu awọn Ọba
Oluwo of Iwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo

Obiozor, nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ Ohanaeze Ndigbo, Olóyè Alex Ogbonnia ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà nílò àwọn ohun tí yóò fi gòkè àgbà àti pé irúfẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹnu Oluwo jáde lè ṣàkóbá fún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan orílẹ̀èdè yìí.

Bákan náà ló fi kun un pé tí Oluwo bá fẹ́ ṣe àgbéga fún olùdíje kan, kò nílò láti máa fẹnu tẹ́mbẹ́lú ẹ̀yà mìíràn nítorí náà ọ̀rọ̀ tí ó tẹnu Ọba alayé náà jáde kò tọ̀nà rárá.

Bẹ́ẹ̀ náà ló sọ wípé kò sí agbègbè kan ní orílẹ̀ ayé tí ènìyàn kò ti ní bá àwọn ẹ̀yà Igbo pàdé nítorí wọ́n jẹ́ akíkanjú tó sì ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti mú ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú bá Nàìjíríà.

Obiozor tún ṣàlàyé pé ẹ̀sùn wí pé àwọn Igbo kìí fẹ́ kí ènìyàn kó dúkìá ní àwọn ìlú wọn kìí ṣe òótọ́ nítorí àwọn gan-an ló ń kọ́le káàkiri ìlú onílùú, fún ìdí èyí wọn kò le so àwọn ènìyàn lọ́wọ́ kọ́ láti kó dúkìá jọ ní ìlú tí wọn náà.

Ìdí nìyí tí àwọn Igbo kò lè jẹ Ààrẹ lórílẹ̀èdè Nàíjíríà - Oluwo

Oluwo of Iwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti kesi awọn ẹya Igbo lorilẹede Naijiria lati tun ero wọn pa lori ero lati jẹ aarẹ ni ọdun 2023.

Oluwo sọ eyi ninu atẹjade to fi lede lati fi ero rẹ han lori idibo sipo aarẹ ni ọdun 2023.

O ni awọn ẹya Igbo kii jẹ ki ọkan awọn ẹya miran to ba wa si ilu wọn balẹ nitori wọn ko lee ni ilẹ nibẹ.

Oluwo of Iwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Imam Fuad tako Oluwo lori wiwe lawani

Oluwo ni ihuwasi wọn yii ko lee jẹ ki wọn moribọ lori igbiyanju wọn lati jẹ aarẹ lorilẹede Naijiria.

''Aibikita iṣesi wọn si awọn ẹya ni Naijiria to ku ko ni jẹ ki awọn eniyan kọ ibi ara si wọn lati dipo aarẹ mu.

''Bi o tilẹ jẹ pe irora ati iya to ṣuyọ lẹyin ogun abẹle to ṣẹlẹ ni Naijiria ti jẹ ki ipinya de ba awọn eniyan, eleyii to si lee pin orilẹede yẹlẹyẹlẹ''

Oluwo nigba to n ba awọn ẹya Igbo kẹdun lori bi ogun abẹlẹ naa ṣe nipa lori wọn, ke si awọn Igbo lati fopin si aṣa ki ẹnikẹni ti kii ṣe ẹya wọn ma l e ra ilẹ ni ẹkun naa.''

'O ni "eleyii jẹ ifasẹyin fun ẹya naa, ti ko si jẹ ki wọn ni ilọsiwaju ninu eto oṣelu.''

Oluwo ni okun to so Naijiria ro ni ifẹ si ẹya orisirisi to wa ni Naijiria, nitorinaa ki ẹnikẹni ma lo eyi lati fa wahala ni agbegbe kan tabi omiran.

Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu bi awọn eniyan ṣe n joko si ile ni ọjọọjọ Aje titi di igba ti wọn yoo fi adari ikọ IPOB, Nnamdi Kanu silẹ ni atimọle to ti n jẹ ẹjọ iditẹmọ ijọba.

''O ṣeni laanu pe awọn ẹya Igbo n kuro ni ile wa si gbogbo agbegbe lorilẹede Naijiria ti wọn a si tẹdo sibẹ.''

''Wọn a kọ ile, wọn a si ra ilẹ sibẹ. Amọ eyi ko ṣeeṣe ni iha ti wọn, nitori wọn ko ni gba lati ta ile fun ẹnikẹni.''

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó

''O ko le jẹ adari lati iru ẹya bẹẹ nitori ko ba igbalode mu, ko si lee mu ilọsiwaju ba orilẹede Naijiria.''

''Mi o le ni igbẹkẹle ninu ẹnikẹni to ba jẹ Igbo lati jẹ Aarẹ mi lorilẹede Naijiria''.

''Nitori naa mo rọ wọn, mo si bẹ wọn lati tun ero wọn pa lori igbese ki ẹnikẹni ma ra ilẹ ni agbegbe wọn. Naijiria kan naa ni wa nitori naa ki a ṣe ara wa ni ọkan.''

Laipẹ yii ni Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrọsheed Adewale Akanbi kesi awọn adari lorilẹede Naijiria lati pe ipade alaafia ti yoo mu iṣọkan ba gbogbo ẹya to wa lorilẹede Naijiria.