Firdaus Abdullahi Oluwo's bride: Ẹ wo bí Olorì tuntun ṣe ń tẹkọ̀ létí lọ sí ààfin Oluwo

Oluwo

Ni bayii ti Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti gbe olori tuntun lati ilu Kano.

Olori naa ti n tẹkọ leti lọ si ilu Iwo bayii si aafin Oluwo ti yoo jẹ ile rẹ tuntun.

oluwo

Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, awọn eeyan to ba olori tuntun naa wa lati Kano atawọn asọju Oluwo ti n tẹkọ leti lọ si ilu Iwo, nibi ti ọpọ awọn araalu ti n duro lati ki olori tuntun naa kaabọ.

Olori Oluwo

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ẹ wo ìgbàradì l'Áàfin de Olorì tuntun Firdaus aya Oluwo ti Iwo

Olori Oluwo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbogbo eto lo ti wa nilẹ fun dídé olori Firdaus Abdullahi tii ṣe ayaba titun fun Ọba Abdullrosheed Adewale Akanbi Oluwo ti ilu Iwo.

Eto ayẹyẹ naa yio waye lọsan oni ni gbagede Aafin Oluwo ti ilẹ Iwo lẹyin ti Ọba abdulllahroshed Adewale ti san owo ori miliọnu kan naira fun idile ayaba rẹ.

Aafin Oluwo

Lana ọjọ Abamẹta ni eto igbeyawo ti ilana ẹya Hausa ni ilu Kano nibi ti Ayaba Firdaus ti dagbere fun baba rẹ to jẹ eekan ilu wọn naa lọhun atawọn mọlẹbi rẹ tii ṣe idile Ọba.

Gẹgẹ bi akọroyin BBC Yoruba ṣe jabọ, baalu ti yio gbe ayaba Firdaus yio balẹ si papa oko ofurufu Murtala Muhammed ni Eko lọsan oni.

Aafin Oluwo

Firdaus, ti o jẹ ọmọ ẹgbọn Emir ti Kano lọwọlọwọ, Alhaji Aminu Ado Bayero, ti gba iwe-ẹkọ diploma ninu imọ ounje sise lati ile ẹkọ gbogbo niṣe, Poly Kano.

Ṣaaju ni a ti fọrọ wa ni lẹnu wo fun awọn ara Ilu Iwo pe bawo ni wọn ṣe n reti Olori tuntun si. Tidunnu tidunnu lawọn ara Iwo fi ni awọn n reti aya tuntun lọọdẹ Ọba wọn.

Koda lara awọn agba ilu ni iyawo kekere ti oun naa, ẹ́ya Hausa ni torinaa Ayaba Firdaus ko lee dabi ajoji si awọn ni Iwo tori ọmọ Naijiria ni.