Tope Alabi: MTN, Glo àti Airtel rugi oyin nítorí orin "Angeli mi"

Tope Alabi

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi

Ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni NPC Records Audioworks Limited ni wọn ti wọ awọn ileeṣẹ ikansiraẹni mẹta kan ni Naijiria, MTN Nigeria Communications Limited, Airtel Networks Limited ati Globacom Limited lọ sile-ẹjọ bayii lori ẹsun jibiti.

Ko si nnkan meji ti wọn lo mu ki ileeṣẹ NPC Records, to jẹ ti Alaaji Tajudeen Bioku gbe awọn ileeṣẹ ikansira-ẹni yii lọ sile-ẹjọ bi ko ṣe ti orin 'Angẹli Mi' ti gbajugbaja onkọrin igbagbọ, Tọpẹ Alabi gbe jade lọdun 2006.

BBC YORUBA gbọ pe ọdun 2005 ni Alhaji Bioku pẹlu Tope Alabi pade nilẹ Amẹrika, nibẹ si ni wọn ti jọ sọ asọyepọ pe ki Tọpẹ Alabi ṣe awo orin kan ti yoo mi igboro titi lede Oyinbo ati Yoruba, ati pe ileeṣẹ NPC Records ọhun un ni yoo gbe orin naa jade.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe rí ọ̀pọ̀ Mílíọ̀nù Nàírà tí mo sì dáà padà fún Ọlọ́pàá lọ́dún 1971 àmọ́ ǹkan t'íjọba sọ rèé - Baba Shonubi

Lẹyin eyi la gbọ pe Tọpẹ Alabi ṣe awo orin 'Angẹli Mi' ati 'My Angel', to si jade l'ọdun 2006.

Ọjọ karun-un, oṣu kinni, ọdun 2006 ni Tọpẹ Alabi ati ileeṣẹ NPC Records tọwọ bọwe adehun, ati pe yoo tun ṣe orin naa si fọnran.

Ki lo wa ninu iwe adehun naa?

Ninu iwe adehun naa la ti gbọ pe ileeṣẹ NPC Records ni yoo ni gbogbo iṣakoso orin yii, ki i ṣe Tọpẹ Alabi, ti wọn si ni Alhaji Bioku ti san gbogbo owo to yẹ fun gbajumọ onkọrin naa.

Tope Alabi

Oríṣun àwòrán, Gbenga Ọladipupọ

Ọjọ kẹsan an, oṣu karun-un, ọdun 2006 naa la gbọ pe Tọpẹ Alabi ṣe iwe ẹri fun ileeṣẹ NPC Records gẹgẹ bi ẹni to ni gbogbo ẹtọ lori orin 'Angẹli Mi' ati 'My Angel'.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

Ọdun mẹfa lẹyin adehun naa la gbọ pe Alaaji Tajudeen Bioku to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ NPC Records gba ileeṣẹ ajọ to n ṣabojuto iwe ẹri fun akọsilẹ lorileede Naijiria, iyẹn Nigerian Copywright Commission, NCC, lati gba iwe ẹri ẹtọ lori awo orin naa.

Tope Alabi

Oríṣun àwòrán, Gbenga Ọladipupọ

Ọjọ kẹta, oṣu kin-in-ni, ọdun 2012 la gbọ pe ajọ NCC fun ileeṣẹ NPC niwe-ẹri lori orin 'Angẹli Mi'.

Bawo ni ọrọ ṣe bẹyin yọ?

BBC Yoruba gbọ pe ọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹsan, ọdun 2020 ni Alaaji Bioku ṣakiyesi pe ileeṣẹ MTN, Airtel ati Glo ti n ta orin naa f'awọn onibara lori ikanni "caller tunes" lai gba aṣẹ lọwọ ileeṣẹ ọhun, ati pe lati ọdun 2011 l'awọn ileeṣẹ ikansira-ẹni mẹta yii ti n ta awọn orin naa.

Wọn ni orin mẹta ninu awo orin naa, 'Angẹli Mi', 'Ẹ Gbe Ga', ati 'Jesu Olurapada' ni wọn ta f'awọn onibara wọn lai gba aṣẹ lọwọ NPC Records.

Ni ti MTN, wọn ni nọmba 703395, 703398 ati 703405 ni wọn fi n ta awọn orin mẹta naa f'awọn onibara wọn, eyi ti wọn sọ pe ṣe ni wọn fẹẹ fi ọwọ ọla gba awọn loju.

Bi aṣiri yii ṣe tu ni wọn sọ pe ọkunrin naa ti sọ fun agbẹjọro rẹ, Oloye Bọlaji Mustapha lati kọwe si MTN lọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹsan, ọdun 2020 lati wa ṣalaye ibi ti wọn ti gba aṣẹ orin ti wọn n lo.

Siwaju si i ni wọn sọ pe ileeṣẹ NPC nipasẹ agbẹjọro wọn tun kọ lẹta si ileeṣẹ Airtel ati Glo lọjọ kẹẹdogun, oṣu keji, ọdun 2021 ati ọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹsan, ọdun 2020 lori ẹsun kan naa yii, ti wọn si ni ko si eyi to dahun niu awọn ileeṣẹ mẹtẹẹta.

BBC YORUBA ri i gbọ pe inu oṣu kẹfa, ọdun yii ni igbẹjọ naa yoo waye nile-ẹjọ giga apapọ to wa nilu Ikoyi, nipinẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó