Happy Easter message 2022: Báyìí ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ṣe ṣàjọyọ̀ ọdún Ajinde káàkiri àgbàyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oni, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ni ayajọ ọdun Ajinde ọdun yii.
Ọdun Ajinde ṣe pataki si awọn ọmọlẹyin Kristi kaakiri agbaye nitori ọjọ naa jẹ ọjọ ti wọn maa n ṣeranti ọjọ ti Jesu ji dide ninu oku.
A ti ṣe akojọpọ awọn aworan bi awọn eeyan ṣe ṣe ọdun naa lagbaye.
- Akẹ́kọ̀ọ́ Seminary tó ń kópa nínú eré "Passion for Christ" kú lórí ìtàgé, bó ṣe ṣẹlẹ̀ nìyí
- Kí ló kan Ẹyin àti Ehoro nínú ìtàn àti ayẹyẹ ọdún Àjíǹde Jésú Krístì?
- Àwọn wo ní olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó ń gbèrò láti rọ́pò Ààrẹ Buhari
- Ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa òṣèré Funke Akindele lẹ́yìn ìtàgé rèé
- Mi ò tíì kú o, àyè ni mo wà! - Akeredolu
- Ta ló ń dá ìwé àṣẹ Falana láti sójú ìdílé Adegoke dúró? Ohun táa mọ̀ rèé
Aworan bi ọdun Ajinde ọdun 2022 ṣe lọ ree kaakiri agbaye

Oríṣun àwòrán, Inpho

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, AFP

Oríṣun àwòrán, Facebook/Deeper Life Bible Church

Oríṣun àwòrán, Other

Oríṣun àwòrán, Church of Nigeria

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, EPA
Bi ọjọ ọdun Ajinde ṣe bẹrẹ ree
Gẹgẹ bii ohun ti iwe mimọ sọ ninu majẹmu tuntun, awọn ara Romu lo kan Jesu mọ agbelebu ni nnkan bii 30 A.D., lẹyin naa ni awọn eeyan rẹ sin oku rẹ niluu Jerusalem.
Ni ọjọ kẹta ni Jesu jinde gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe Mathew 28:1-10.
Lẹyin awẹ lẹnti to maa n waye fun ogoji ọjọ ni awọn ọmọlẹyin Kristi kaakiri agbaye maa n ṣe ajọyọ ọdun ajinde ni ọjọ Aiku 'Easter Sunday."
Ọjọ "Ash Wednesday" ni awẹ lẹnti naa si maa n bẹrẹ.
Amọ ṣaaju ọjọ ọdun ajinde yii ni awọn Kristẹni maa n ṣe iranti ayayjọ ọjọ ti Jesu gun kẹtẹkẹtẹ wọ ilu Jerusalem, ti wọn n pe ni " Palm Sunday."
Ọjọ Ẹti to tẹle "Palm Sunday'" ni ayajọ ọjọ Ẹti rere, iyẹn "Good Friday."

Oríṣun àwòrán, AFP
Kini pataki ọdun Ajinde?
Pataki ọdun Ajinde ni lati sami ijiya ti Jesu Kristi jẹ́ lori igi agbelebu.
Awon onigbagbo tun gbagbọ́ pe o wa lati fi se iranti iku Jesu Kristi lati fun awọ́n elẹ́sẹ̀ ni ominira lati bọ́ lọ́wa igbekun aisi igbala.
O tun wa fun lati sami ayọ́ ati ireti ajinde lẹ́yin oku ti awọ́n Onigbagbọ́ gbagbọ́ ninu re.
Eyi waye leyin ti Jesu Kristi jinde lọ́jọ́ kẹ́ta kuro ninu isa oku ni eyi to je ireti nla pe o ti gba kọ́kọ́ra lọ́wọ́ iku atinisa oku fun enikeni to ba gbagbo ninu re.












