Ile Ife Kidnap: Àwọn afurasí ajínigbé kó sí gbaga Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, ABUJA FACTS
Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Osun ní àwọn tí nawọ́ gán àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ajínigbé méjì ní ìlú Ile Ife lẹ́yìn tí wọ́n kọjú ìjà síra.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Osun, Yemisi Opalola fi léde lọ́jọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kẹrin ọdún 2022 ní ọwọ́ tẹ àwọn afurasí náà nígbà tí wọ́n jí ọkùnrin kan gbé ní agbègbè ibi tí àwọn Fulani ń gbé ní ìlú Ile Ife.
Opalola ní àwọn ń sa gbogbo ipá láti ri dájú wí pé Ìpínlẹ̀ Osun wà ní ààbò pípé fún gbogbo tolórí tẹlẹ́mù tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ náà.
- Fídíò Chrisland, ikú Sylvester Oromoni, àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọ gbì tó wáyé láwọn ilẹ ẹ̀kọ́ girama
- Iṣẹ́ ilé kíkọ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ Dejo Tunfulu lẹ́yìn tó jáde láyé
- kìí ṣe ẹ̀bi wa wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àṣemáṣe - ile ẹ̀kọ́ Chrisland
- Bí mo ṣe rí iṣẹ́ ní UK rèé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú - Ọmọ Naijiria sọ ìrírí rẹ̀
- Ǹkan tí a mọ̀ rèé nípa ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ tó wáyé láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chrisland
- Mo ti tọrọ aṣọ àti yẹrín etí rí, kí n tó leè ṣe àwo orin - Tope Alabi
- Ọlọ́run ló sọ fún mi kí n lọ dupò ààrẹ Naijiria ní 2023, ohun tó sọ fún mi rèé - Ìmàámù Afeez Akinola
- Ìjọba fìdíhẹẹ́ ló yẹ ká kéde lẹ́yìn sáà Buhari, Ìwé òfin Nàìjíríà kò kájúẹ̀ - Afe Babalola
Ó ṣàlàyé pé ní ọjọ́ Àìkú ní nǹkan bí ago mọ́kànlá àbọ̀ òwúrọ̀ ni ẹnìkan lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ Ọlọ́pàá "C" Division, Aganhun Ilé Ifẹ̀ wí pé àwọn afurasí ajínigbé ya wọ agbègbè Erefe ní òpópónà Ondo tí wọ́n sì jí ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Muhammed Gembu gbé lọ.
"Lésẹ̀ kan ni àwọn agbófinró lọ síbẹ̀ tí wọ́n sì rí àwọn méjì mú nínú wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n kọjú ìjà síra."
Bákan náà ló ní àwọn rí ẹni tí wọ́n jí gbé náà gbà kalẹ̀ láì farapa pẹ̀lú àtìlẹyìn àwọn fijilanté.
Ó ní ní kété tí ìwádìí bá ti parí ni àwọn yóò kó wọn lọ sí ilé ẹjọ́.
Opalola fi kún pé kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Osun wá rọ àwọn ará ìlú láti máa fi gbogbo ohun tó bá ń ṣẹlẹ̀ ní agbègbè wọn tó Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá létí kí wọn le lé àwọn oníṣẹ́ ibi jìnà ní ìpínlẹ̀ náà.
















