Interview Tips: Ó lé ní ìgbà 400 tí mo ''apply'' fún iṣẹ́ tí wọn kò mú mi kí ìyanu tó ṣẹlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Ruth Ossai
Ni Oṣu Kẹta, ọdun 2020 ni Ruth Ozavize Ossai kuro ni Naijiria lọ si Ilẹ Gẹẹsi, ti ko si lero pe oun le wa iṣẹ to igba irinwo ki ohun to ri iṣẹ to fẹran.
Iṣẹ onimọ ẹrọ, chemical engineering, ni Ruth kọ ni fasiti ki o to ya bara lọ si idi iṣẹ eto ilera lẹnu iṣẹ.
Ruth to jẹ ẹni ọgbọn ọdun sọ iriri rẹ fun BBC Pidgin ohun ti oju rẹ ri lasiko to n wa iṣẹ amọ ti ko mikan titi ti ọwọ rẹ fi tẹ ohun ti o oun wa.
- Ǹkan tí a mọ̀ rèé nípa ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ tó wáyé láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chrisland
- Mo ti tọrọ aṣọ àti yẹrín etí rí, kí n tó leè ṣe àwo orin - Tope Alabi
- Ọlọ́run ló sọ fún mi kí n lọ dupò ààrẹ Naijiria ní 2023, ohun tó sọ fún mi rèé - Ìmàámù Afeez Akinola
- Ìjọba fìdíhẹẹ́ ló yẹ ká kéde lẹ́yìn sáà Buhari, Ìwé òfin Nàìjíríà kò kájúẹ̀ - Afe Babalola
- Kọjú sí iṣẹ́ ìwàásù táa fí rán ọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wà darapọ̀ mọ́ òṣèlú - Ilééṣé ààrẹ sí Father Kukah
- Àwọn adigunjalè já wọ ilé ounjẹ lọ́jọ́ ọdún Ajínde, wo ọṣẹ́ tí wọ́n ṣe
- Nítorí orin 'Angeli mi' ti Tope Alabi kọ, iléeṣẹ́ MTN, Glo àti Airtel dèrò ilé ẹjọ́
- 'Ọkọ Osinachi sọ fún un pé kó sùn sílè aṣẹ́wó dípò ilé mi'
- Ìjọba Eko ti iléẹ̀kọ́ Chrisland pa torí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ láàrín àwọn àkẹ́kọ̀ọ́
Ni akọkọ Ruth ri iṣẹ ni Oṣu Kẹfa, ọdun 2020, amọ kii ṣe iru iṣẹ to yan laayo, eyi ko si mu pinnu lati ma ṣe wa iṣẹ mọ.
Igbiyanju rẹ lati ri iṣẹ lo mu ki o ri iṣẹ pẹlu ile iṣẹ to n risi eto ilera awọn oṣiṣẹ, DHU, lẹyin igba to le ni irinwo to ti n wa iṣẹ ati igba marundinlọgbọn to ti lọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo.
''Igbiyanju lati ri iṣẹ ti mo ka gan an, ti ọdun 2021 ni ko si 2020 nibẹ.''
''Ni igba ti emi ati ọkọ mi ṣe iṣiro rẹ ni ari pe o le ni igba irinwo.''
''Gbogbo bi mo ṣe n wa iṣẹ yii ko jẹ ki n ko iyan ara mi kere, amọ mi o ni ilọsiwaju lẹnu iṣẹ ti mo yan laayo.
''Nkan ẹyọkan to tabuku ilọsiwaju lẹnu iṣẹ mi ni pe laarin ọdun meji ti mo fi kuro ni Nigeria lọ si UK, mi o ṣe iṣẹ kankan to jọmọ iṣẹ ti mo yan laayo."
''Mi o ni iriri iṣẹ kankan to jọ mọ iṣẹ ti mo yan laayo, to si yọ silẹ amọ mo dupẹ pe mi o ṣe ọlẹ laarin ọdun meji naa.''
Awọn nkan ti ko jẹ ki n tete ri iṣẹ ni...
- Oye imọ nipa iṣẹ ti mo ni
- Aimọ bi wọn ṣe n wa ọkọ
- Ibi ti mo n wa iṣẹ si jina si ile
Bi o ṣe le se aṣeyọri ti o ba n wa iṣẹ ni yii
- Mọ nipa ile iṣẹ to n wa iṣẹ si naa daadaa
- Ma saniyan pe o mọ gbogbo nkan
- Ka iwe daadaa, ki o wo awọn ibeere to ṣeeṣe ki wọn bere ni ọwọ rẹ
- Ṣiṣẹ takuntakun ki o le jẹ iwuri fun ara rẹ ati bi o ṣe n gbe ara rẹ.
- Gbogbo igba ni ki o pinnu lati mọ si ju ti tẹlẹ lọ.
Nigba ti Ruth ti ri iṣẹ bayii,ọpọlọpọ nkan lo yipada ni igbesi aye rẹ.
''Mo fẹran iṣẹ ti mo n ṣe bayii nitori eyi ti mo yan laayo ni, inu mi ati ti awọn ọga mi ati akẹgbẹ mi si dun''.
Bakan naa lo fikun un pe awọn ọmọ Naijiria kan ro pe o dẹrun lati ri iṣẹ ti wọn ba ti de Ilẹ Gẹẹsi amọ ko ri bẹẹ fun gbogbo eniyan.
Ruth pari ọrọ rẹ pẹlu imọran pe ki awọn ti ko ba dẹrun fun ma mikan nitori yoo dara.















