Easter Celebration robbery in Anambra: Àwọn adigunjalè gba fóònù, ohun ìní àwọn ènìyàn nílé oúnjẹ

Awọn adigunjale ti ṣekọlu si ile ounjẹ kan to wa ni agbegbe Oko, ni ẹgbẹ ileẹkọ gbogboniṣe Federal Polytechnic, Oko.
Awọn adigunjale naa wọ ile ounjẹ igbalode kan lati ja awọn eniyan ni ole amọ ti ko si ẹnikẹni to fi ara pa.
Awọn ti wọn ja ni ole wọnyii n ṣe faaji lọwọ ni Ọjọ Ajinde ni awọn adigunjale yii yawọ ibẹ, ti wọn si gba awọn ohun ini awọn eniyan ni ọwọ wọn to fi mọ foonu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìyà tó jẹ́ mi lẹ̀yìn tí mo kúrò nílé ọkọ lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà kọjá sísọ - Iyabo Ojo
- Ẹ wo ''Spider Man'' tó di agbálẹ̀ ní Osogbo
- Ìjọba Eko ti iléẹ̀kọ́ Chrisland pa torí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ láàrín àwọn àkẹ́kọ̀ọ́
- Nítorí orin 'Angeli mi' ti Tope Alabi kọ, iléeṣẹ́ MTN, Glo àti Airtel dèrò ilé ẹjọ́
- Ìdí nìyí tí àwọn Igbo kò lè jẹ Ààrẹ lórílẹ̀èdè Nàíjíríà - Oluwo
- Wo èsì ilé ìtura Zanzibar tí ọmọbìnrin yìí ní wọ́n fẹ́ fipá bá òun lòpọ̀ níbẹ̀
- Kókó pàtàkì márùn ùn rèé tí Bíṣọ́bù Kukah fi sọ ọ̀rọ̀ gbá ààrẹ Buhari nínú ìwàásù ọdún àjínde
- Ìpadàbọ̀sípò àti ọrọ̀ yóò wà fún Nàìjíríà - Osinbajo gbàdúrà
- Ọlópàá 16 farapa nínú ikọlù tó wáyé torí àwọn kàn gbèrò láti dáná sún Quran
Arakunrin Iyke Orji loju opo ikansiraẹni Facebook ni wọn ko pa ẹnikẹni bẹẹ si ni wọn ko ṣe ẹnikẹni ni ijamba.
''Ohun ti wọn ṣe ni pe wọn wa sibẹ, ti ko si si ọlọpaa kankan tabi ẹṣọ alaabo to wa ni agbegbe naa to da wọn duro.''
''Ọkọ ọlọpaa to wa nibẹ ti gomina Soludo fi si agbegbe agọ ọlọpaa Oko ko da awọn adigunjale naa duro lasiko ti wọn wa si ile ounjẹ, Sophia Fast food ti wọn ṣẹṣẹ ṣi ni agbegbe naa ni Ekwulobia.
Amọ ẹlomiran to sọrọ ti ko fi ẹsẹ mulẹ ni oṣeeṣe ko jẹ awọn to n ba ile ounjẹ tuntun naa figagbaga ni wọn ran awọn adigunjale naa.
Ileesẹ ọlọpaa ni ki awọn to kagbako isẹlẹ naa wa fẹjọ sun ni agọ wọn:

Oríṣun àwòrán, NPF
Nigba to n fesi lori isẹlẹ yii, ileesẹ ọlọpaa to wa nipinlẹ Anambra ti wa rọ awọn eeyan to se agbako isẹlẹ idigunjale naa lati jade wa sọrọ sita.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra, Toochukwu Ikenga ninu atẹjade to fisita nipa isẹlẹ naa lọjọ Aje ni ọrọ ẹnu awọn eeyan naa ti isẹlẹ idigunjale naa soju wọn, ni yoo se iranwọn lati se iwadii lori isẹlẹ naa.
Bakan naa lo fikun pe eyi yoo tun ran awn osisẹ ọlọpaa lọwọ lati dena irufẹ isẹlẹ naa lọjọ iwaju ni agbegbe naa..


















