Chrisland Rape: Ẹ̀sùn ìbàlópọ̀ láàrin akẹ́kọ̀ọ́ kó iléẹ̀kọ́ sí wàhálà

Oríṣun àwòrán, CHRISLAND SCHOOL
Ijọba ipinlẹ Eko ti ti gbogbo ileẹkọ Chrisland to wa ni ipinlẹ Eko pa.
Eyi ko yẹ lori iṣẹlẹ to ṣẹ s'awọn akẹkọọ rẹ kan to rinrinajo lọ si ilu Dubai lorilẹede UAE laipẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti ajọ to n gbogun ti iwa ipa laarin ẹbi ati iṣẹlẹ kotọ nipa Ibalopọ nipinlẹ Eko, (DSVRA) fi sita lọjọ Aje, wọn ni iwadii ti bẹrẹ lori ẹsun ifipabanilopọ to waye laarin awọn akẹkọọ ileẹkọ naa kan ti wọn jẹ majeṣin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Nítorí orin 'Angeli mi' ti Tope Alabi kọ, iléeṣẹ́ MTN, Glo àti Airtel dèrò ilé ẹjọ́
- Ìdí nìyí tí àwọn Igbo kò lè jẹ Ààrẹ lórílẹ̀èdè Nàíjíríà - Oluwo
- Wo èsì ilé ìtura Zanzibar tí ọmọbìnrin yìí ní wọ́n fẹ́ fipá bá òun lòpọ̀ níbẹ̀
- Kókó pàtàkì márùn ùn rèé tí Bíṣọ́bù Kukah fi sọ ọ̀rọ̀ gbá ààrẹ Buhari nínú ìwàásù ọdún àjínde
- Ìpadàbọ̀sípò àti ọrọ̀ yóò wà fún Nàìjíríà - Osinbajo gbàdúrà
- Ọlópàá 16 farapa nínú ikọlù tó wáyé torí àwọn kàn gbèrò láti dáná sún Quran
"O ṣe pataki lati jẹ ki mutumuwa mọ pe gbogbo iwadi nlọ lọwọ ni akoso awọn ajọ gbogbo to yẹ bii ileeṣẹ eto ẹkọ.
To fi mọ ajọ eto ẹkọ to yanranti, ileeṣẹ ọrọ ọdọ ati idagbasoke awujọ, ileeṣẹ eto idajọ pẹlu ajọ to n gbogun ti iwa ipa laarin ẹbi ati iṣẹlẹ kotọ nipa Ibalopọ nipinlẹ Eko, (DSVRA).
A si ti gbe ẹsun iwa ọdaran to jẹyọ nibẹ tọ ọga ọlọpaa nipinlẹ yii lọ."
Bawo ni isẹlẹ naa se de ori ayelujara:
Gbajumọ ọga olorin kan t'orukọ rẹ n jẹ Ubi Franklin lo kọkọ gbe ọrọ naa sori ikanni ayelujara Twitter ni ọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹrin ọdun 2022.
Sugbọn ko darukọ ileẹkọ ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori nigba naa
Atẹjade Twitter rẹ lo wa fa pọ awuyewuye lori ayelujara.
Ajọ DSVRA ni pẹlu awọn ẹsun to jẹyọ lori iṣẹlẹ naa, awọn ti pese eto ilera ati itọju ọpọlọ fun awọn ti ọrọ naa kan.
Igbesẹ ti ajọ DSVRA n gbe lori isẹlẹ naa:
Ajọ DSVRA ni "oun ti n gbe igbesẹ tubọ fi ọkan araalu balẹ pe ijọba ipinlẹ Eko ko f'ọrọ aabo ati igbayegbadun awọn ọmọde ṣere.
Paapaa lati rii pe gbogbo awọn ileeṣẹ to n ba awọn ewe ṣiṣẹ nipinlẹ Eko n ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu aṣẹ ofin (Executive Order NO.EO/AA08 of 2016), ti gomina pa lori didaabo bo awọn ọmọde."
Bakan naa lajọ DSVRA tun lo anfani atẹjade naa lati kilọ fun gbogbo awọn to ba n pin fidio tabi aworan Ibalopọ to ni ṣe pẹlu ọmọde pe ẹwọn ọdun mẹrinla ni wọn fi n ṣere.
Mama ọmọ to wa ninu fidio ibalopọ naa sọrọ lori isẹlẹ:
Nibayii o, obinrin kan ti jade lori ayelujara lati kede pe oun ni Mama ọmọ ti iṣẹlẹ naa kan.
Obinrin naa ṣalaye pe awọn ko mọ si iṣẹlẹ naa ayafi igba ti obi kan ti ọmọ rẹ pẹlu n lọ sile iwe naa pe akiyesi wọn.
Gbogbo akitiyan lati kan si ileẹkọ Chrisland lati sọrọ lori iroyin ti n ja ranyinranyin nipa wọn yii ni wọn n fesi pe awọn yoo fi atẹjade sita laipẹ.
















