Chrisland School girl Video: Ẹ̀kọ́ tí a rí kọ́ rèé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìbálòpọ̀ láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Chrisland School

Oríṣun àwòrán, Chrisland School

Ẹwọn ọdun mẹrinla fun ẹnikẹni to ba pin fidio ibalopọ

Lara awọn ẹkọ pataki to ṣuyọ lori iṣẹlẹ ẹsun ibalopọ laarin awọn akẹkọọ ileẹkọ Chrisland ni ipa ti awọn obi nko ni igbeaye awọn ọmọ ati ewu ati ijiya to wa fun fiimu ibalopọ laarin awọn ọmọde.

Eyi ati awọn ẹsun miran ni ileeṣẹ to n risi ọrọ iwa ipa nipinlẹ Eko, Lagos State Domestic and Sexual Violence Response Agency (DSVRA) n ṣewadii lọwọ.

Ẹwọn ọdun mẹrinla fun ẹnikẹni to ba pin fidio ibalopọ

Ijọba ipinlẹ Eko ti kilọ fun awọn ara ilu lati ṣọra fun pinpin fidio awọn akẹkọọ ileẹkọ Chrisland nibi ti wọn ti n ba ara wọn lopọ.

Awọn alaṣẹ ni ẹnikẹni to ba ṣe atunpin fidio naa lori ẹrọ ayelujara tunmọ si pe ẹni naa ni ifẹ si ibalopọ laaarin awọn ọmọde, eleyii ti ijiya rẹ jẹ ẹwọn ọdun mẹrinla.

Ijọba ni awọn ti yoo foju wina ofin ni awọn to gbe jade, awọn to pin, awọn to gba a ati awọn to ni aworan ibalopọ awọn ọmọde naa lọwọ.

Àkọlé fídíò, Blessing Olajide: Ẹ̀bí akẹ́kọ̀ọ́jáde fásitì Ilorin tí wọn pa ṣàlàyé ikú rẹ̀

Fidio naa di ilumọọka lori ẹrọ ayelujara

Lai naani awọn ikilọ ti ijọba fi lede lori fidio ibalopọ laarin awọn ọmọde ni ileẹkọ Chrisland, fidio na jale ja oko.

Ọjọ diẹ sẹyin ni fidio naa jade sori ayelujara ti iṣẹlẹ naa si waye lasiko ti awọn akẹkọọ naa lọ si Dubai fun ayẹyẹ ere idaraya ni Ọjọ Kẹwa si Ikẹtala, Oṣu Kẹta, ọdun 2022.

Amọ ẹni kan to fi atẹjade lede lori iṣẹlẹ naa ni kii ṣe ifipabanilopọ lo waye, bi ko ṣepe awọn ọmọ naa ṣe ere ti o ba to bee to si da nkan miran.

Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko n ṣewadi lọwọ...

Kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Abiodun Alabi ti kede ni Ọjọ Aje pe awọn n ṣe iwadii fidio to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara lọwọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii naa niiṣe pẹlu iye awọn akẹkọọ to kopa ninu fidio naa, ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Bakan naa ni wọn yoo ṣewadii oye igba ti wọn ti dunkoko mọ akẹkọọ kan ti wọn ni ko lọ ṣẹ oyun lai si imọ awọn obi rẹ lori igbesẹ naa.

Iya ọmọbinrin Chrisland ṣe fidio lati ṣalaye bi isẹlẹ naa ṣe waye...

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni iroyin gbe e pe awọn alaṣẹ ileẹkọ naa ti ni ki akẹkoọ naa lọ rọkun ni ile fun akoko yii naa.

Amọ obinirin kan to jade lati sọ wi pe oun ni iya ọmọ naa ni wọn fi ipa ba ọmọ oun lopọ ni ti wọn si tun fi iya jẹ ẹ .

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe rí ọ̀pọ̀ Mílíọ̀nù Nàírà tí mo sì dáà padà fún Ọlọ́pàá lọ́dún 1971 àmọ́ ǹkan t'íjọba sọ rèé - Baba Shonubi
Chrisland School girl video: Parenting, child pornography, tins we learn from Lagos school scandal

Oríṣun àwòrán, Chrisland School

Àkọlé àwòrán, Chrisland School

Iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ijọba ipinlẹ Eko ti ileẹkọ Chrisland pa...

Ijọba ipinlẹ Eko ti kede ki wọn ti ileẹkọ Chrisland pa ati awọn ẹka rẹ.

Iṣẹlẹ to waye naa lo mu ki ijọba gbe igbesẹ ọhun.

Ṣe awọn obi lo ni ẹbi ni abi ileẹkọ

Iṣẹlẹ ileẹkọ Chrisland ti mu ki ọpọlọpọ eniyan fi ero wọn han lori iṣẹlẹ naa ati ipa ti obi n ko lori ọmọ ati ti ileẹkọ.

Lara awọn to sọrọ lori ẹrọ ikansiraẹni ni ileẹkọ naa lo jẹbi iṣẹle oun ni gbogo ona.

Amọ awọn kan ni iṣẹ itọju ọmọ ti le ju ti tẹlẹ lọ, ti eniyan gbọdọ ṣe abojuto wọn daadaa.

Nibayii, oju yoo wa lara ileeṣẹ ọlọpaa ati ijoba ipinlẹ Eko lori iṣẹlẹ naa.

Amọ ohun ti ọpọ eniyan n bere fun ni idajọ ododo ati eto ilera ihuwasi ọmọniyan fun gbogbo awọn ti ọrọ naa kan.