Afghan Girls U-turn: Taliban yí ìpinnu padà lórí fífi ààyè gba akẹ́kọ́ọ̀bìnrin láti padà sí kíláàsì

Aworan awọn akẹkọọ to fẹ wọ kilasi ti wọn dapa lỌjọru

Ikọ alakatakiti ẹsin Islaamu nii, Taliban ti palu ẹnu da lori fifaaye gba awọn akẹkọbinrin lati kẹkọ nile ẹkọ girama lorileede Afghanistan.

Ni bayi wọn tun sọ pe idajọ n bọ lori iru aṣọ ti wọn gbọdọ wọ,

Jakejado ilẹ naa lo yẹ ki wọn ti ṣi awọn ile ẹkọ pada lẹyin idiwọ to waye lati igba ti Taliban gba ijọba loṣu Kẹjọ ọdun to kọja.

Amọ bayi ileeṣẹ eto ẹkọ ti kede pe awọn ko ni ṣi ile ẹkọ girama ti eleyi si ti fa idaamu laarin awọn obi ati akẹkọọ.

Niṣe lawọn akẹkọọ bẹrẹ si ni sunkun tawọn obi si n faraya lori igbesẹ ti wọn gbe yi.

Ọpọ lo ti n fi ayọ ati idunnu wọn han lori pe awọn yoo pada sileẹkọ.

Igbesẹ yi waye lẹyin ọsẹ kan ti ileeṣẹ eto kọ kede pe awọn yoo si awn ile ẹkọ to fi mọ tawọn obinrin nilẹ naa lỌjọru.

Arakunrin kan ti ko f ki wọn darukọ rẹ sọ fun BBC pe inu ibanujẹ ni ọmọ rẹ obinrin wa lati igba ti awọn alaṣẹ Taliban ko jẹ ko wọ ileẹkọ rẹ.

''Bi nkankan ba ṣẹlẹ si ọmọ mi laburu, mi o ni forijin awọn ikọ Taliban''

Ọjọ buruku loni jẹ fawọn obinrin Afghanistan

Malala Yousafzai

Malala Yousafzai to jẹ ilumọọka ajafẹtọmọniyan ọmọ Pakistan sọ pe awọn ti mọ pe Taliban yoo maa wa awawi ni ati pe wọn ko ṣetan lati faaye gba akẹkọbinrin ni ile ẹkọ.

Ninu fọnran fidio kan to fi sita lojuopo Youtube lo ti fi ọrọ yi lede.

O ni ko jẹ nkankan tuntun pe Taliban ko fẹ kawọn obinrin kẹkọ.

'' A ti gbọ nigba kan ri, a gbọ ni ọdun 1996,koda a tun gbọ loni ni ọdun 2022 pe wọn yoo lo awawi aṣọ ileẹkọ lati fi kọdi awọn akẹkọbinrin lati kẹkọ''

O tẹsiwaju pe ohun tawọn Taliban n gbero ni kawọn obinrin ma kẹkọ kọja ileẹkọ alakọbẹrẹ lọ.