Olasupo Afeez Ibadan Muslim Cleric declares for presidency: Ohun tí Ọlọ́run sọ fún mi nìyí tí mo fi fẹ́ dupò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, The Nation
Alfa Olasupo Afeez Akinola naa ti darapọ mọ awọn to kéde láti dupò Ààrẹ Naijiria ní 2023.Imaamu ẹsin Islam yii, Olasupo Afeez Akinola kede erongba rẹ lati dupo aarẹ Naijiria lọdun 2023 ni ọjọ diẹ sẹyin.
Lori ayelujara, aworan rẹ wa kaakiri to gbe aworan ara rẹ ati ipo to n lọ fun dani.

Oríṣun àwòrán, The Nation
Olasupo kede erongba rẹ niwaju awọn ọmọ ìjọ rẹ n'ilu Ibadan lọjọ Aiku.Iroyin ti ileeṣẹ iwe iroyin Naijiria, The Nation fi sita ni, Olasupo sọ pe Ọlọrun lo pàṣẹ fun oun pe ki oun dije fun ipo aarẹ, nitori pe ninu òṣì ni awọn ọmọ Naijiria n gbe. "Eyi to mu ki nini adari to bẹru Ọlọ́run jẹ dandan."
Àwọn adigunjalè já wọ ilé ounjẹ lọ́jọ́ ọdún Ajínde, wo ọṣẹ́ tí wọ́n ṣeAbẹ asia ẹgbẹ́ oselu All Progressives Congress, APC, ni Afeez ti fẹ́ dije. Lati bi oṣù kan ni awọn to nifẹ lati dupo ipo aarẹ Naijiria, ninu idibo gbogboogbo ti yoo waye l'oṣu Kejì, ọdun 2023, ti n kede erongba wọn. Lara wọn ni igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo, aṣiwaju ẹgbẹ́ APC, Bola Tinubu, gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, minisita fun eto irinna, Rotimi Amaechi, to fi mọ igbakeji aarẹ nigba kan, Atiku Abubakar, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Alfa Akinola, lo fẹ́ dabi ẹni pe ọjọ ori rẹ kere ju laarin gbogbo awọn ọkunrin yii. Yàtọ̀ si Arabinrin Khadija Okunnu, ti oun naa kede lati dije fun ipo naa.


























