Rotimi Amaechi declares for 2023 presidency: Rotimi Amaechi, mínísítà fétò ìrìnnà kéde ìpinnu láti díje fún ipò ààrẹ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, channelstv
Minisita feto irinna lorilẹede Naijiria, Rotimi Amaechi ti kede pe oun naa nifẹ lati dije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 2023.
Lọjọ Satide, lasiko to n ba ọgọrọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC sọrọ nibi eto kan nilu Port Harcourt, nipinlẹ̀ Rivers, lẹkun aringbungbun Gusu orilẹede Naijiria ni Amaechi ṣe ikede naa.
Ninu akori ọrọ apilẹkọ rẹ to pe ni "itẹsiwaju pẹlu ọkan akin' nibi eto idupẹ kan ni papa iṣere Adokiye Amiesiamaka, Amaechi ṣalaye pe ipinnu oun lati dije kii ṣe eyi to rọrun, ṣugbọn oun ni igbagbọ pe ọdun mẹtalelogun ti oun ti lo lati fi sin orilẹede Naijiria loniruuru ipo oṣelu ti fun oun ni igbaradi to tọ fun iṣẹ adari Naijiria.
"Ẹyin ọmọ Naijiria, mo duro si iwaju yin loni lati kede ipinnu mi ati lati fi iwe ipinnu mi lelẹ lati dije fun ipo aarẹ."
Irinajo Rotimi Amaechi lagbo oṣelu

Oríṣun àwòrán, Rotimi amaechi
Ni ọdun 1965 ni a bi Rotimi Amaechi, ṣugbọn lọdun 1999 lorukọ rẹ bẹrẹ si nii gbilẹ lagbo oṣelu lorilẹede Naijiria nigba di olori ile aṣofin ipinlẹ Rivers.
Ipo yii lo di mu di ọdun 2007 ki o to di gomina ipinlẹ naa laarin ọdun 2007 si 2015.
Lasiko ti Ọgagun Muhammadu Buhari fi n dije lati di aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 2014 si 2015, Rotimi Amaechi ni oludari agba fun igbimọ ipolongo ibo fun un nigba naa.
Ni kete ti Aarẹ Muhammadu Buhari de ori oye lo ti yan an gẹgẹ bi minisita feto iriina lati igba naa titi di asiko yii.
Awọn oloṣelu to ti jade lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Bateso23
Bola Ahmed Tinubu:
Bọla Tinubu jẹ ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC, ohun si ni gomina ipinlẹ Eko laarin ọdun 199 si 2007.
Rochas Okorocha:
Okorocha ni gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, igba akọkọ rẹ si kọ niyi lati dije, lẹyin to ti kọkọ gbe igba ibo fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu AA nigba kan ri.
Rochas Okorocha fi erongba rẹ lati dije han ninu lẹta kan to kọ ranṣẹ si aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Ahmad Lawan lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kini ọdun 2022.
Khadija Okunnu -Lamidi:
Oun ni obinrin akọkọ to jade lati kede pe oun fẹ dije fun ipo aarẹ lọdun 2023. Ko tii kede ẹgbẹ oṣelu kankan ti o wa bayii na. Ohun to sọ ni pe ẹgbẹ oṣelu to ba ni iran kan naa pẹlu oun loun yoo ba lọ.

Oríṣun àwòrán, twitter/Omotoyosi Adeolu Adetayo
Dele Momodu:
loṣu kẹta ọdun 2023 ni Dele Mọmọdu kede pe oun naa yoo dije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP.
Igba akọkọ kọ niyi ti Dele Mọmọdu yoo maa fifẹhan si didije fun ipo aarẹ ni Naijiria.
Yahaya Bello:
Yahaya Bello ni gomina ipinlẹ Kogi lọwọ yii. Laipẹ yii loun pẹlu kede pe oun naa nifẹ si ipo aarẹ lọdun 2023.












