Nkechi Blessing: Gbajúmọ̀ òṣèré, Nkechi Blessing ṣàlàyé pé òun ti kán lu agbami ìfẹ́ míràn lẹ́yín ìjákulẹ̀ àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Opeyemi Falegan

Nkechi Blessing pẹlu Ọpẹyẹmi Falẹgan

Oríṣun àwòrán, Inkechi blesing Sunday/ Instagram

"Mi o ki n ṣe ọlẹ o. Mi o dẹ ki n ṣe ara awọn obinrin to n sun pẹlu awọn ọkunrin lati lowo tabi di ọlọrọ."

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Nkechi Blessing ti ṣalaye pe ori oju opo ayelujara Instagram loun ti n ri pupọ owo ti oun pa.

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu gbajumọ sọrọsọrọ ori afẹfẹ, Daddy Freeze, Nkechi Blessing ṣalaye pe owo ti oun n ri lori awọn iṣẹ ti oun n ri lori ayelujara.

"Mi o le gba kere ju ẹgbẹrun lọna ọdunrun naira, N300,000 lori awọn ipolowo ti mo ba gbe si oju opo Instagram."

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin jade pe ajọṣepọ laarin gbajumọ oṣere naa ati ọrẹkurin ololufẹ rẹ ti fori ṣanpọn.

Ninu ifọrọwerọ rẹ naa, Nkechi Blessing ni lati ipilẹ pẹpẹ ni ọrẹkunrin rẹ naa ti sọ pe ki oun maṣe reti ohunkohun to pọ pupọ ninu ajọṣepọ wọn naa.

Blessing ni irọ lo pọ ju ninu ohun gbogbo ti awọn eeyan kan n sọ kiri nipa oun pe oun tilẹ tun gba ọkọ ọlọkọ nigba kan.

O ni ọrẹkunrin oun naa fi ara rẹ han oun gẹgẹ bi ẹni to fẹ lo oun lati di ilumọọka.

O fi kun un pe gbogbo igbesẹ ti oun gbe lati mu ki ọrẹkunrin oun tẹlẹ naa ri ajọṣepọ wọn kuro lori ayelujara ki wọn lee ṣeto ayelujara.

Gbajumọ oṣere naa ni pupọ awọn eeyan ti wọn n pariwo pe ki oun ati ọrẹkunrin oun o gbe ọrọ gbogbo nipa ajṣepọ wọn kuro lori ayelujara naa ni wọn o tun maa pariwo pe boya wọn ti pin garri ni ni kete ti wọn ko ba ri wọn lori ayelujara mọ.

Ki ni Nkechi Blessing Sunday sọ nipa akoba ayelujara si ajọṣepọ ọrọ ifẹ rẹ?

Nkechi Blessing pẹlu Ọpẹyẹmi Falẹgan

Nkechi Blessing pẹlu Ọpẹyẹmi Falẹgan

Oríṣun àwòrán, Nkechi blessing/instagram

O wa ṣalaye pe akoba ti ọrọ ayelujara ṣe fun ajọṣepọ ifẹ oun ko kere rara.

Nkechi Blessing wa tun yọju rẹ sita pe lẹyin ti ajọṣepọ oun pẹlu Ọpẹyẹmi David Falẹgan foriṣanpọn ni oun ti bẹrẹ ajọṣepọ pẹlu ẹlomiran loṣu kini ọdun 2022.

"Daddy Freeze, mo ti sọ ọ tẹlẹ o. Emi ti ni ọrẹkunrin ololufẹ miran o. Aye wa da? Mo ti ni ọrẹkunrin miran lati oṣu kini ọdun 2022."

O ni oun ko raye ọrọ ifẹ mọ bayii o. Oun ti gbe ọrọ ifẹ ti si ẹgbẹ kan. O fi kun un pe lati oṣu kini loun ti sọ fun Ọpẹyẹmi pe oun ti kuro ni ajọṣepọ wọn ati pe ọpẹyẹmi nikan lo n tan ara rẹ pẹlu ajọṣepọ naa.

Ki ni ibẹrẹ ọrọ wọn?

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

Ọpẹyẹmi Falẹgan, Ọrẹkunrin Nkechi Blessing Sunday tẹlẹ lo wa sori ayelujara lati fọ aṣọ idọti nipa ajọṣepọ wọn ni gbangba pẹlu ẹsun pe awọn mejeeji ko ni ajọṣepọ kankan mọ.

Ninu oniruuru fidio to fi soju opo rẹ lọjọ Ẹti ni Falẹgan ti sọ yanya pe idi ti gbajumọ̀ oṣere tiata naa ṣe gba lati fẹ oun ni "owo ati ibalopọ."

ṣugbọn Nkechi funrarẹ ti jade lati sọrọ pe ọrọ to jina sootọ leyi ati pe ọlẹ ti ko fẹ ṣiṣẹ ni Ọpẹyẹmi ọrẹkunrin oun tẹlẹ naa, bẹẹ ni ọrọ ti ko ṣe maa sọ ni aijafafa rẹ tọrọ ba di ọrọ ere ori ẹni.