National grid collapse: Ìtàkùn àpapọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná 'National grid'ní Nàìjíríà tún ti paná pi

itakun opo ina mọnamọna

Oríṣun àwòrán, vanguard news

Àkọlé àwòrán, Igba karun un niyi ti itakun ina mọnamọna lorilẹede Naijiria maa pana pii lọdun 2022 nikan.

Omilẹgbẹ awọn ilu lorilẹede Naijiria ninu eyi ti olu ilu orilẹede naa, Abuja wa, ni wọn tun kanlu agbami okunkun birimu-birimu lọjọ Ẹti lẹyin ti okun ipese ina apapọ, 'National grid' tun ja lọjọ Ẹti.

Awọn ileeṣẹ ipese ina manamana lorilẹede Naijiria ni wọn kede ijakulẹ itakun ina manamana orilẹede naa eleyi to mu ko di igba karun un lọdun 2022 nikan lẹyin ti ọpọlọpọ awọn agbegbe lorilẹede naa ti wa ninu okunkun.

Ileeṣẹ apinna mọnamọna fun ẹkun Kaduna, iyẹn Kaduna Electricity Distribution Company ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe, "Ẹyin Onibara wa, igbimọ iṣakoso Ileeṣẹ apinna mọnamọna fun ẹkun Kaduna kabamọ lati fi to yin leti pe aisina ọba to n waye ko ṣẹyin bi itakun ina mọnamọna apapọ orilẹede yii tun ṣe ja kulẹ."

Ni nnkan bii agogo mẹfa kọja iṣẹju mọkandinlọgbọn irọlẹ ọjọ Ẹti ni itakun apapọ ina mọnamọna Naijiria tun ja eleyi to jẹ igba kẹta laarin oṣu kan sẹyin bayii.

Bakan naa ni ileeṣẹ apinna mọnamọna fun agbegbe Abuja, iyẹn Abuja Electricity Distribution, Company, ileeṣẹ apinna mọnamọna fun agbegbe ilu Jos, Jos Electricity Distribution Company, ileeṣẹ apinna mọnamọna fun agbegbe ilu Eko, Eko Electricity distribution company, pẹlu fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lalẹ ọjọ Ẹti.

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

Ileeṣẹ apinna mọnamọna fun agbegbe Eko, EKDC ni tirẹ tilẹ tẹsiwaju lati sọ pe, laarin agogo mẹsan an owurọ si mẹta ọsan lọjọ Satide, ọjọ kẹsan an oṣu kẹrin ọdun 2022, ko ni si ina ni eyikeyi awọn agbegbe to n pin ina de.

"Eyi wa lati fun ileeṣẹ to n tan ina mọnamọna kalekako lorilẹede Naijiria, TCN lanfani lati ṣe awọn atunṣe gbogbo to ba yẹ si itakun ina Tower #9 ati #10 to wa lagbegbe oju opo Ajah/Alagbon 330kv line."

Igba melo ni itakun apapọ ina mọnamọna lorilẹede Naijiria ti dẹnu kọlẹ?

Igba karun un niyi ti itakun ina mọnamọna lorilẹede Naijiria maa pana pii lọdun 2022 nikan.

Ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kini ni itakun ina mọnamọna naa kọkọ dakẹ iṣẹ lọdun 2022 .

itakun opo ina mọnamọna

Oríṣun àwòrán, Businessday.ng

Àkọlé àwòrán, Lati ọdun 2013 ti ijọba apapọ ti sọ ẹka ipese ina ọba di ti aladani, igba aadoje ọtọọtọ ni itakun apapọ ina mọnamọna lorilẹede Naijiria ti pana pii

Ni Ọjọ Aje ọjọ kẹrinla ọdun 2022, itakun apapọ ina mọnamọna lorilẹede Naijiria tun daku ni nnkan bii agogo mọkanla ku ogun iṣẹju, ti omiran si tun waye ni nnkan bii agogo marun un kọja iṣẹju mẹwaa lọjọ Iṣẹju ọjọ karundinlogun oṣu kẹta kan naa

Ko tan sibẹ loṣu kẹta ọdun 2022. Nigba to tun ti di ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹta yii kan naa nui omiran tun waye.

Àkọlé fídíò, Jimi Solanke: Bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ eré òṣùpá láyé àtijọ́ táa mú ìtàn Yorùbá sísọ dé America padà

Ọrọ ina mọnamọna lorilẹede Naijiria ti di ariigbọdọ wi ikun imu baale fun ọpọlọpọ ọmọ orilẹede Naijiria lati ijọba de ijọba pẹlu bi ko ṣe si ọna abayọ fun okunkun birimu tawọn ọmọ orilẹede naa n koju nigba gbogbo.

Lati ọdun 2013 ti ijọba apapọ ti sọ ẹka ipese ina ọba di ti aladani, igba aadoje ọtọọtọ ni itakun apapọ ina mọnamọna lorilẹede Naijiria ti pana pii pẹlu oniruuru awawi latọdọ ijọba ni gbogbo asiko naa.