Dino Melaye: Àsìkò ti to fún ọ̀rọ̀ ''Zoning'' ipò ààrẹ ní Naijiria láti dópin

Dínò Mèláye

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye/Facebook

Ṣẹnetọ Dino Melaye ti tabukuu bi orilẹede Naijiria ṣe ma n yan ipo lati ẹkun kan de omiran lai fi ti ki eniyan kunjuwọn ṣe.

Dino Melaye lasiko to n kopa ninu eto kan lori ẹrọ amohunmaworan ti Channels TV ti igbeṣẹ naa ko mu idagbasoke eto oṣelu ni Naijiria dani.

''Lẹyin ọgọta ọdun gẹgẹ bi orilẹede olominira, ko bojumu ki a ṣi ma n sọrọ nipa pinpin ipo nipa ẹkun si ẹkun.''

''A gbọdọ dagba soke lati iṣejọba aye atijo si iṣejọba to kunjuwọn ju ti ọr ẹkun kan si omiran.''

Aṣofin tẹlẹri naa ni iru pinpin ipo lati ẹkun kan si omiran ki n waye ni awọn orilẹede to ti dagba bi orilẹede Amẹrika.

Lori eto naa lo ti ran awon eniyan leti lori igbiyanju rẹ gẹgẹ bi aṣofin lati gbe abadofin kalẹ lati ma fi ti ọrọ ipinlẹ ṣe ohunkohun ni Naijiria.

''Ohun to yẹ ni ki a fun awọn to ba kunjuwọn ni orilẹede Naijiria lai fi ti ọrọ ipinlẹ ṣe lanfani''.

Dino Melaye ni awọ̀n gomina ati awọn oṣelu lo jẹ alajẹtan lorilẹede Naijiria ti iya fi n jẹ awọn eniyan wọn amọ wọn n sọ wi pe ijọba apapọ n fi eto wọn dun wọn.

''Lẹyin ogun ọdun iṣejọba tiwantiwa ati ọgọta ọdun iṣejọba olominira, ko yẹ ki a ṣi ma a dapara ipo lati ẹkun kan si omiran.''

Bio tilẹ jẹpe awọn eniyan to n lọgun ki iṣejọba ipo aarẹ ma a lọ lati ẹkun kan si omiran ki o le kari, Dino Melaye ni ọpọlọpọ orilẹede ni Africa lo dabi Naijiria ti wọn kii si ṣe ọrọ igun si igun.