Wo ìdí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fi ti ilé ìwòsàn níbi tí alákọ́bí ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò ìkúnlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Chibike Nwachukwu
Agba adura ni pe ki alaboyun bi wẹrẹ lọjọ ikunlẹ, ka si gbọ ohun iya ati ọmọ lalaafia.
O ṣeni laanu pe adura yii ko di gbigba nigba ti alaboyun kan padanu ẹmi rẹ lasiko ikunlẹ ni ile iwosan kan nipinlẹ Eko.
Iṣẹlẹ yii ti mu ki ijọba ipinlẹ Eko ti ile iwosan naa pa lẹyin ti wọn gbọ pe wọn ko kunju osunwọn nidi iṣẹ wọn
Ijọba gbe igbesẹ yii lẹyin iroyin to gbode pe arabinrin Vivian Nnwachukwu to jẹ alakọbi ku sile iwosan naa nigba to n rọbi.
Ileeṣẹ ijọba to n mojuto awọn ile iwosan (HEFAMAA) lo sọ agadagodo si ile iwosan yii.
- Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Akeredolu tó gbá ìyàwó mi létí ó bá má lọ lọ́fẹ̀ẹ́ - Ọkọ Aláboyún
- Wo ǹkan tí o kò mọ̀ nípa ESABOD tí òun àti Lizzy Anjorin jọ ń fi omi èpè wẹ ara wọn
- Mi o lè sọkún torí ǹkan ọkùnrin tí kò lè gbò mí jìgì-jìgì ju ìṣẹ́jú àáyá méjì lọ - Nkechi Blessing
- Ọgá Báńkì tàá tú sílẹ̀, tórí ọjọ́ orí rẹ̀ àti ọlá Ramadan ni - Ajínigbé
Ki lo ṣẹlẹ ?
Lọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹta ni iṣẹlẹ yi ti waye ni adugbo Okota.
Chibuike Nwachukwu,ọkọ arabinrin naa sọ fun BBC pe iyawo oun ko koju ipenija kankan lasiko to loyun.
''Ilu Enugu ni mo wa nigba ti iṣẹlẹ naa waye''
Arakunrin naa sọ pe ''ile iwosan naa ni iyawo mi ti ṣe eto itọju alaboyun ante-natal titi di ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹta 2022''

Oríṣun àwòrán, Chibike Nwachukwu
"O ṣe gbogbo nkan to yẹ to fi mọ awọn ayẹwo ti esi rẹ si sọ pe ko si nkankan to ṣe''
Nwachukwu ni iyawo rẹ n fi atẹjisẹ ranṣẹ lori foonu lati jẹ ki oun mọ bi nkan ti ṣe nlọ ni ile iwosan nigbato wọ ile igbẹbi.
"Ile iwosan naa lo sọ pe ko bẹ́rẹ si ni maa bọwa nigba ti apo omi rẹ ja.
Bo ti ṣe de ibẹ ni wọn fun labẹrẹ ki igbẹbi baa le ya''
O fi kun pe''Mi o ribi baa sọrọ titi ti o fi di nkan bi ago meji oru ti ọmọ iya mi lobinrin pe mi pe wọn nilo ẹjẹ''
'Oku iyawo mii ni mo deba lati irinajo''
Nwachukwu sọ pe oun gbiyanju lati wa ẹjẹ ti wọn beere amọ ara bẹrẹ si ni fu oun nigba ti ''wọn ni wọn fẹ ge ile ọmọ iyawo mi.Eleyi lẹyin igba ti wọn lo ti padanu ọpọ ẹjẹ''
Arakunrin naa sọ pe niṣe niyawo rẹ ẹni ọdunmejidinlọgbọn padanu ẹmi rẹ ki oun to ribi pada de Eko lati Enugu.
O ni lẹda ẹjẹ marun un ni wọn fun iyawo rẹ.
O ni nitori iru nkan ti o n desi igbọ rẹ lati Eko, oun ko jafara lati wa baalu ti yoo gbe wa si Eko ni kiakia lalẹ ọjọ naa.
"Bi mo ṣe de ile iwosan naa oku iyawo mi ni mo ba ni aaye kan ti wọn pe ni aaye iṣẹ abẹ tiata''
'Ile iwosan naa ko gba ontẹ ijọba'
Ariwo ti ọkọ iyawo yii pa loju opo ayelujara lo mu ki ọrọ naa deti igbọ ijọba ti wọn si da si.
Kọmisana ilera nipinlẹ Eko, Akin Abayomi fi soju opo Twitter rẹ to si ni ijọba ti ti ile iwosan naa pa.
O sọ pe ẹka ileeṣẹ ilera ipinlẹ Eko, (Hefamaa) lo ti ile iwosan naa pa.
Amọ akọwe agba ileeṣẹ naa, Dokita Abiola Idowu sọ pe awọn ti ile iwosan naa ''nitori aitẹle ilana ti ijọba gbe kalẹ''
O ni iwadii awọn fihan pe ile iwosan naa ko forukọsilẹ lọdọ awọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
"Aiforukọ silẹ wọn tako ofin atunto eto ilera ọdun 2006''
''Eyi tunmọ si pe ọna ẹburu ni ile iwosan naa n gba ṣiṣẹ.
Ikọ wa tun ri pe wọn ko ni oṣiṣẹ to to dede iye to yẹ ki wọn ni''
O ni ajọ awọn n ṣewadii iku arabinrin Vivian Nwachukwu ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati pe ile iwosan naa yoo wa ni titi pa lati fi daabo bo araalu.
Ẹwẹ, ọkọ arabinrin naa sọ pe agbe lo fọ, omi ko danu, ọmọkunrin ti iyawo rẹ bi wa laaye amọ o n gba itọju ni ile iwosan.
Mọlẹbi ti da ọjọ Kẹsan oṣu Kẹrin gẹgẹ bi ọjọ ti wọn yoo sinku alaboyun naa.

















